Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 18:11 - Yoruba Bible

11 “Bákan náà, gbogbo àwọn ọrẹ ẹbọ, ati àwọn ẹbọ fífì tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi, yóo jẹ́ tiyín. Mo fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ lọkunrin ati lobinrin, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn títí lae. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ mímọ́ ninu wọn lè jẹ ẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Eyi si ni tirẹ; ẹbọ igbesọsoke ẹ̀bun wọn, pẹlu gbogbo ẹbọ fifì awọn ọmọ Israeli: emi ti fi wọn fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati fun awọn ọmọ rẹ obinrin pẹlu rẹ, bi ipín lailai: gbogbo awọn ti o mọ́ ninu ile rẹ ni ki o jẹ ẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 “Èyí tún jẹ́ tìrẹ pẹ̀lú: ohunkóhun tí a bá yà sọ́tọ̀ lára ẹ̀bùn ọrẹ fífì àwọn ọmọ Israẹli. Mó fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín tí yóò máa ṣe déédé nínú ìdílé rẹ, tí o bá wà ní mímọ́ ni o le jẹ ẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 18:11
10 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn kí ẹ jẹ igẹ̀ tí ẹ bá fi rú ẹbọ fífì ati itan ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ní ibi mímọ́, ìwọ ati àwọn ọmọkunrin rẹ ati àwọn ọmọbinrin rẹ, nítorí pé ìpín tìrẹ ni, ati ti àwọn ọmọkunrin rẹ, ninu ẹbọ alaafia, tí àwọn eniyan Israẹli rú.


Kí ó yọ àkàrà kọ̀ọ̀kan kúrò lára ẹbọ kọ̀ọ̀kan, kí ó fi rúbọ sí OLUWA; yóo jẹ́ ti alufaa tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran ẹbọ alaafia náà sára pẹpẹ.


OLUWA sọ fún Aaroni pé, “Ìwọ, ati àwọn ọmọ rẹ, ati ìdílé baba rẹ ni yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n bá dá ní ibi mímọ́. Ṣugbọn ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn alufaa bá dá.


Níbi mímọ́ ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ wọ́n. Àwọn ọkunrin ààrin yín nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ wọ́n nítorí wọ́n jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ.


“Gbogbo àwọn ẹbọ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi ni mo fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ, lọkunrin ati lobinrin, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn títí lae. Èyí jẹ́ majẹmu pataki tí mo bá ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ dá.”


OLUWA sọ fún Aaroni pé, “Mo ti fún ọ ní gbogbo ohun tí ó kù ninu àwọn ohun tí wọ́n bá fi rúbọ sí mi, ati gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli bá yà sọ́tọ̀. Ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni mo fún gẹ́gẹ́ bi ìpín yín títí lae.


“Ohun tí yóo jẹ́ ti àwọn alufaa lára ẹran tí àwọn eniyan bá fi rúbọ nìyí, kì báà jẹ́ akọ mààlúù tabi aguntan ni wọ́n wá fi rúbọ, wọn yóo fún alufaa ní apá ati ẹ̀rẹ̀kẹ́ mejeeji, ati àpòlùkú rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan