Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 18:10 - Yoruba Bible

10 Níbi mímọ́ ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ wọ́n. Àwọn ọkunrin ààrin yín nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ wọ́n nítorí wọ́n jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Bi ohun mimọ́ julọ ni ki iwọ ki o ma jẹ ẹ: gbogbo ọkunrin ni yio jẹ ẹ; mimọ́ ni yio jẹ́ fun ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ẹ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ jùlọ, gbogbo ọkùnrin ni ó gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Ó gbọdọ̀ kà á sí mímọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 18:10
13 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn náà, ọkunrin náà wí fún mi pé, “Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ ìhà àríwá ati àwọn yàrá ìhà gúsù tí wọ́n kọjú sí àgbàlá ni àwọn yàrá mímọ́. Níbẹ̀ ni àwọn alufaa tí ń rú ẹbọ sí OLUWA yóo ti máa jẹ ẹbọ mímọ́ jùlọ. Níbẹ̀ ni wọn yóo máa kó àwọn ẹbọ mímọ́ jùlọ sí; ati àwọn ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, nítorí ibẹ̀ jẹ́ ibi mímọ́.


Ibi mímọ́ ni kí ẹ ti jẹ ẹ́, nítorí pé òun ni ìpín yín ati ti àwọn ọmọ yín, ninu ẹbọ sísun OLUWA, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni OLUWA pa á láṣẹ fún mi.


“Kí ló dé tí ẹ kò fi jẹ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ní ibi mímọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé, ohun tí ó mọ́ jùlọ ni, tí ó sì jẹ́ pé ẹ̀yin ni OLUWA ti fún, kí ẹ lè máa ru ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ eniyan yìí, kí ẹ sì máa ṣe ètùtù fún wọn níwájú OLUWA.


Alufaa náà yóo pa àgbò náà níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ti ẹbọ sísun ninu ibi mímọ́, nítorí pé ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi jẹ́ ti alufaa, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; ohun mímọ́ patapata ni.


Ó lè jẹ ohun jíjẹ ti Ọlọrun rẹ̀, kì báà ṣe ninu èyí tí ó mọ́ jùlọ tabi ninu àwọn ohun tí ó mọ́.


Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo jẹ ìyókù, láì fi ìwúkàrà sí i. Ibi mímọ́ kan ninu àgbàlá Àgọ́ Àjọ ni wọ́n ti gbọdọ̀ jẹ ẹ́.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọkunrin ninu àwọn ọmọ Aaroni lè jẹ ninu rẹ̀, èyí ni ìlànà mi títí ayérayé láàrin arọmọdọmọ yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan ẹbọ wọnyi yóo di mímọ́.”


Alufaa tí ó bá fi rúbọ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo jẹ ẹ́; níbi mímọ́, ninu àgbàlá Àgọ́ Àjọ ni kí ó ti jẹ ẹ́.


Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ alufaa tí ó bá jẹ́ ọkunrin lè jẹ ninu ohun ìrúbọ yìí; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ.


Gbogbo ọkunrin, lára àwọn alufaa lè jẹ ninu rẹ̀, wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.


“Bákan náà, gbogbo àwọn ọrẹ ẹbọ, ati àwọn ẹbọ fífì tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi, yóo jẹ́ tiyín. Mo fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ lọkunrin ati lobinrin, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn títí lae. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ mímọ́ ninu wọn lè jẹ ẹ́.


Ninu gbogbo ẹbọ mímọ́ tí a kò sun lórí pẹpẹ, ẹbọ ọrẹ, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, tí wọn ń rú sí mi yóo jẹ́ mímọ́ jùlọ fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan