Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 18:1 - Yoruba Bible

1 OLUWA sọ fún Aaroni pé, “Ìwọ, ati àwọn ọmọ rẹ, ati ìdílé baba rẹ ni yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n bá dá ní ibi mímọ́. Ṣugbọn ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn alufaa bá dá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Iwọ ati awọn ọmọ rẹ, ati ile baba rẹ pẹlu rẹ, ni yio ma rù ẹ̀ṣẹ ibi-mimọ́: ati iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma rù ẹ̀ṣẹ iṣẹ-alufa nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Olúwa sọ fún Aaroni pé, “Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ àti ìdílé baba rẹ ni yóò ru gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá fún ilé tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run, àti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóò máa ru ẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ àlùfáà yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 18:1
22 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Aaroni bá ń rú ẹbọ mímọ́, tí àwọn ọmọ Israẹli ti yà sọ́tọ̀ fún èmi OLUWA, kinní bí àwo pẹrẹsẹ yìí yóo máa wà níwájú orí rẹ̀, kí wọ́n lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ mi.


Yóo rí èrè àníyàn ọkàn rẹ̀, yóo sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi, olódodo, yóo dá ọpọlọpọ eniyan láre, yóo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn.


Gbogbo wa ti ṣáko lọ bí aguntan, olukuluku wa yà sí ọ̀nà tirẹ̀, OLUWA sì ti kó ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa lé e lórí.


“Lẹ́yìn náà, fi ẹ̀gbẹ́ rẹ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì di ìjìyà àwọn ọmọ ilé Israẹli lé ara rẹ lórí. O óo ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún iye ọjọ́ tí o bá fi dùbúlẹ̀.


“Kí ló dé tí ẹ kò fi jẹ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ní ibi mímọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé, ohun tí ó mọ́ jùlọ ni, tí ó sì jẹ́ pé ẹ̀yin ni OLUWA ti fún, kí ẹ lè máa ru ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ eniyan yìí, kí ẹ sì máa ṣe ètùtù fún wọn níwájú OLUWA.


Kí wọ́n má baà mú àwọn eniyan náà dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n sì kó ẹ̀bi rù wọ́n nípa jíjẹ àwọn ohun mímọ́ wọn; nítorí èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.”


“Àwọn alufaa gbọdọ̀ pa àwọn òfin mi mọ́, kí wọ́n má baà dẹ́ṣẹ̀ nítorí rẹ̀, kí wọ́n sì kú nítorí àwọn òfin mi tí wọ́n bá rú. Èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.


Ẹ óo sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ogoji ọdún. Ọdún kọ̀ọ̀kan yóo dípò ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ninu ogoji ọjọ́ tí àwọn amí fi wo ilẹ̀ náà. Ẹ óo rí ibinu mi.


OLUWA ti fún ẹ̀yin ati àwọn ọmọ Lefi yòókù ní anfaani yìí, ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀ ń ṣe ojú kòkòrò sí iṣẹ́ alufaa.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́ yóo kú, ṣé gbogbo wa ni a óo ṣègbé ni?”


Kọ orúkọ Aaroni sí ọ̀pá tí ó wà fún ẹ̀yà Lefi, nítorí pé ọ̀pá kan ni yóo wà fún olórí kọ̀ọ̀kan.


Mose kó gbogbo àwọn ọ̀pá náà siwaju OLUWA ninu Àgọ́ Ẹ̀rí.


“Bákan náà, gbogbo àwọn ọrẹ ẹbọ, ati àwọn ẹbọ fífì tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi, yóo jẹ́ tiyín. Mo fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ lọkunrin ati lobinrin, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn títí lae. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ mímọ́ ninu wọn lè jẹ ẹ́.


“Mú ẹ̀yà Lefi wá siwaju Aaroni alufaa, kí wọ́n sì máa ṣe iranṣẹ fún un.


Ní àkókò yìí, OLUWA ya àwọn ẹ̀yà Lefi sọ́tọ̀ láti máa gbé Àpótí Majẹmu OLUWA, ati láti máa dúró níwájú OLUWA láti ṣe iṣẹ́ ìsìn, ati láti máa yin orúkọ rẹ̀, títí di òní olónìí.


Kí ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn aṣiwaju yín lẹ́nu, kí ẹ máa tẹ̀lé ìlànà wọn. Nítorí wọ́n ń ṣe akitiyan láìṣe àárẹ̀ láti tọ́jú yín, pẹlu ọkàn pé wọn yóo jíyìn iṣẹ́ wọn fún Ọlọrun. Ẹ mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ayọ̀ fún wọn, ẹ má jẹ́ kí ó jẹ́ ìrora. Bí ẹ bá mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ìrora fún wọn, kò ní ṣe yín ní anfaani.


Nítorí Olórí Alufaa tí a ní kì í ṣe ẹni tí kò lè bá wa kẹ́dùn ninu àwọn àìlera wa. Ṣugbọn ó jẹ́ ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bíi wa, ṣugbọn òun kò dẹ́ṣẹ̀.


Òun fúnrarẹ̀ ni ó ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi, kí á baà lè kú sí ẹ̀ṣẹ̀, kí á wà láàyè sí òdodo. Nípa ìnà rẹ̀ ni ẹ fi ní ìmúláradá.


Mika fi ọdọmọkunrin náà jẹ alufaa, ó sì ń gbé ilé Mika.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan