Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 17:8 - Yoruba Bible

8 Nígbà tí ó wọ inú Àgọ́ Ẹ̀rí ní ọjọ́ keji, ó rí i pé ọ̀pá Aaroni tí ó wà fún ẹ̀yà Lefi ti rúwé, ó ti tanná, ó ti so èso alimọndi, èso náà sì ti pọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 O si ṣe, ni ijọ́ keji ti Mose wọ̀ inu agọ́ ẹrí lọ; si kiyesi i, ọpá Aaroni fun ile Lefi rudi, o si tú, o si tanna, o si so eso almondi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì Mose wọ inú àgọ́ ẹ̀rí lọ, ó sì rí ọ̀pá Aaroni, tí ó dúró fún ẹ̀yà Lefi, kì í ṣe wí pé ó hù nìkan Ṣùgbọ́n ó rúwé, ó yọ ìtànná, ó sì so èso almondi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 17:8
13 Iomraidhean Croise  

Ìtàkùn náà ní ẹ̀ka mẹta, bí ewé rẹ̀ ti yọ, lẹsẹkẹsẹ, ni ó tanná, ó so, èso rẹ̀ sì pọ́n.


OLUWA yóo na ọ̀pá àṣẹ rẹ tí ó lágbára láti Sioni. O óo jọba láàrin àwọn ọ̀tá rẹ.


Bí igi ápù ti rí láàrin àwọn igi igbó, ni olùfẹ́ mí rí láàrin àwọn ọmọkunrin. Pẹlu ìdùnnú ńlá ni mo fi jókòó lábẹ́ òjìji rẹ̀, èso rẹ̀ sì dùn lẹ́nu mi.


Tí ó bá di ìgbà náà, ẹ̀ka igi OLUWA yóo di ohun ẹwà ati iyì. Èso ilẹ̀ náà yóo sì di ohun ògo ati àmúyangàn fún àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá kù.


Gbogbo igi inú igbó yóo mọ̀ pé èmi, OLUWA, ni èmi í sọ igi ńlá di kékeré, mà sì máa sọ igi kékeré di ńlá. Mà máa sọ igi tútù di gbígbẹ, má sì máa mú kí igi gbígbẹ pada rúwé. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe.”


Ṣugbọn a fa àjàrà náà tu pẹlu ibinu, a sì jù ú sílẹ̀. Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn mú kí ó gbẹ, gbogbo èso rẹ̀ sì rẹ̀ dànù. Igi rẹ̀ tí ó lágbára gbẹ, iná sì jó o.


Iná ṣẹ́ lára igi rẹ̀, ó sì jó gbogbo ẹ̀ka ati èso rẹ̀. Kò sì ní igi tí ó lágbára mọ́, tí a lè fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún ọba. Dájúdájú ọ̀rọ̀ arò ni ọ̀rọ̀ yìí, ó sì ti di orin arò.


Ó sì sọ fún Kora ati àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ní ọ̀la OLUWA yóo fi ẹni tí í ṣe tirẹ̀ tí ó jẹ́ ẹni mímọ́ hàn. Ẹni tí OLUWA bá sì yàn ni yóo mú kí ó súnmọ́ òun.


Ọ̀pá ẹni tí mo bá yàn yóo rúwé; bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí ọ.”


Mose kó àwọn ọ̀pá náà jáde kúrò níwájú OLUWA, ó kó wọn wá siwaju àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn wò wọ́n, olukuluku àwọn olórí sì mú ọ̀pá tirẹ̀.


Níbẹ̀ ni pẹpẹ wúrà wà fún sísun turari, ati àpótí majẹmu tí a fi wúrà bò yíká. Ninu àpótí yìí ni apẹ wúrà kékeré kan wà tí wọ́n fi mana sí ninu, ati ọ̀pá Aaroni tí ó rúwé nígbà kan rí, ati àwọn wàláà òkúta tí a kọ òfin mẹ́wàá sí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan