Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 17:7 - Yoruba Bible

7 Mose kó gbogbo àwọn ọ̀pá náà siwaju OLUWA ninu Àgọ́ Ẹ̀rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Mose si fi ọpá wọnni lelẹ niwaju OLUWA ninu agọ́ ẹrí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Mose sì fi ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú Olúwa nínú àgọ́ ẹ̀rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 17:7
9 Iomraidhean Croise  

Ìṣirò ohun tí wọ́n lò fún kíkọ́ àgọ́ ẹ̀rí wíwà OLUWA nìyí: Mose ni ó pàṣẹ pé kí ọmọ Lefi ṣe ìṣirò àwọn ohun tí wọ́n lò lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni, alufaa.


Ṣugbọn kí ó fi wọ́n ṣe alákòóso Àgọ́ Ẹ̀rí ati àwọn ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀. Àwọn ni yóo máa ru Àgọ́ náà ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀, wọn yóo sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níbẹ̀. Wọ́n óo pa ibùdó wọn yí Àgọ́ náà ká.


Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi ni kí wọ́n pàgọ́ yí Àgọ́-Ẹ̀rí ká, kí àwọn tí kì í ṣe ọmọ Lefi má baà súnmọ́ Àgọ́ náà, kí n má baà bínú sí àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Lefi ni yóo máa ṣe ìtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà.”


Bí àwọn eniyan náà ti ń gbèrò láti sọ wọ́n lókùúta pa ni wọ́n rí i tí ògo OLUWA fara hàn ní Àgọ́ Àjọ.


Kí o kó wọn sílẹ̀ níwájú Àpótí Ẹ̀rí ninu Àgọ́ Àjọ mi, níbi tí mo ti máa ń pàdé rẹ.


Mose sọ èyí fún àwọn ọmọ Israẹli. Olórí àwọn ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan mú ọ̀pá wọn wá fún Mose, gbogbo rẹ̀ jẹ́ mejila, ọ̀pá Aaroni sì wà ninu wọn.


Pe àwọn eniyan rẹ, àwọn ọmọ Lefi, ẹ̀yà ìdílé baba rẹ, pé kí wọn wà pẹlu rẹ, kí wọ́n sì máa jíṣẹ́ fún ọ nígbà tí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ bá ń ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Ẹ̀rí.


Ní ọjọ́ tí wọn pa Àgọ́ Àjọ, èyí tí í ṣe Àgọ́ Ẹ̀rí, ìkùukùu bò ó. Ní alẹ́, ìkùukùu náà dàbí ọ̀wọ̀n iná.


“Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí kan ní aṣálẹ̀. Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀, ó sì pàṣẹ fún un pé kí ó ṣe àgọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí òun ti fihàn án tẹ́lẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan