Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 17:2 - Yoruba Bible

2 “Gba ọ̀pá mejila láti ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀pá kọ̀ọ̀kan láti ọwọ́ olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, kí o sì kọ orúkọ olukuluku sí ara ọ̀pá tirẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si gbà ọpá kọkan lọwọ wọn, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, lọwọ gbogbo awọn olori wọn gẹgẹ bi ile awọn baba wọn ọpá mejila: ki o si kọ́ orukọ olukuluku si ara ọpá rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí o sì gba ọ̀pá méjìlá lọ́wọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ olórí ìdílé ẹ̀yà ìran wọn, kọ orúkọ ènìyàn kọ̀ọ̀kan sí ara ọ̀pá rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 17:2
18 Iomraidhean Croise  

Ọ̀pá àṣẹ ọba kì yóo kúrò ní ilé Juda, arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo sì máa jọba, títí tí yóo fi dé ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ni ín; gbogbo ìran eniyan ni yóo sì máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.


Wọ́n kọ orúkọ àwọn alufaa ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún sókè ni wọ́n kọ orúkọ wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ipò wọn ati ìpín wọn.


OLUWA yóo na ọ̀pá àṣẹ rẹ tí ó lágbára láti Sioni. O óo jọba láàrin àwọn ọ̀tá rẹ.


Eniyan burúkú kò ní ní àṣẹ lórí ilẹ̀ àwọn olódodo, kí àwọn olódodo má baà dáwọ́ lé ibi.


Ta òróró yìí sí ara àgọ́ àjọ, ati sí ara àpótí ẹ̀rí,


Mú ọ̀pá yìí lọ́wọ́, òun ni o óo máa fi ṣe iṣẹ́ ìyanu.”


OLUWA bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló wà ní ọwọ́ rẹ yìí?” Ó dáhùn pé, “Ọ̀pá ni.”


Iná ṣẹ́ lára igi rẹ̀, ó sì jó gbogbo ẹ̀ka ati èso rẹ̀. Kò sì ní igi tí ó lágbára mọ́, tí a lè fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún ọba. Dájúdájú ọ̀rọ̀ arò ni ọ̀rọ̀ yìí, ó sì ti di orin arò.


A ti pọ́n ọn láti fi paniyan; a ti fi epo pa á, kí ó lè máa kọ mànà bíi mànàmáná. Ọ̀rọ̀ yìí kìí ṣe ọ̀rọ̀ àríyá; nítorí àwọn eniyan mi kọ̀, wọn kò náání ìkìlọ̀ ati ìbáwí mi.


Mò ń dán àwọn eniyan mi wò, bí wọ́n bá sì kọ̀, tí wọn kò ronupiwada, gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn, Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.


OLUWA, fi ọ̀pá rẹ tọ́ àwọn eniyan rẹ, àní agbo aguntan ìní rẹ, tí wọn ń dá gbé ninu igbó, láàrin ilẹ̀ ọgbà; jẹ́ kí wọ́n máa jẹko ní Baṣani ati ní Gileadi bí ìgbà àtijọ́.


OLUWA sọ fún Mose pé,


Kọ orúkọ Aaroni sí ọ̀pá tí ó wà fún ẹ̀yà Lefi, nítorí pé ọ̀pá kan ni yóo wà fún olórí kọ̀ọ̀kan.


Ní ọjọ́ tí Mose gbé Àgọ́ Àjọ dúró, tí ó sì ta òróró sí i tòun ti gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, ati pẹpẹ pẹlu gbogbo ohun èlò rẹ̀,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan