Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 17:10 - Yoruba Bible

10 OLUWA sọ fún Mose, pé, “Dá ọ̀pá Aaroni pada siwaju Àpótí Ẹ̀rí, kí ó lè jẹ́ àmì ìkìlọ̀ fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ Israẹli, kí wọ́n sì lè dẹ́kun kíkùn tí wọn ń kùn sí mi, kí wọ́n má baà kú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú ọpá Aaroni pada wa siwaju ẹrí, lati fi pamọ́ fun àmi fun awọn ọlọ̀tẹ nì; ki iwọ ki o si gbà kikùn wọn kuro lọdọ mi patapata ki nwọn ki o má ba kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá Aaroni padà wá síwájú ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí ààmì fún àwọn ọlọ̀tẹ̀. Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má ba à kú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 17:10
23 Iomraidhean Croise  

Ààrin àwọn kinniun ni mo dùbúlẹ̀ sí, àwọn tí ń jẹ eniyan ní ìjẹ ìwọ̀ra; eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ ati ọfà, ahọ́n wọn sì dàbí idà.


Mose wí fún wọn pé, “Àṣẹ tí OLUWA pa nìyí: ‘Ẹ fi ìwọ̀n omeri kan pamọ́ láti ìrandíran yín, kí àwọn ọmọ yín lè rí irú oúnjẹ tí mo fi bọ́ yín ninu aṣálẹ̀ nígbà tí mo ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá.’ ”


Aaroni bá gbé e kalẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA ti pa fún Mose.


Máa gbọ́, ìwọ ọ̀run, sì fetí sílẹ̀, ìwọ ayé Nítorí pé OLUWA ń sọ̀rọ̀ Ó ní, “Lẹ́yìn tí mo bọ́ àwọn ọmọ, tí mo tọ́ wọn dàgbà tán, ọ̀tẹ̀ ni wọ́n dì sí mi.


Láti ìgbà Gibea ni Israẹli ti ń dẹ́ṣẹ̀; sibẹ wọn kò tíì jáwọ́ ninu ẹ̀ṣẹ̀. Ṣé ogun kò ní pa wọ́n ní Gibea?


Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀ níwájú àwọn eniyan náà.


“Ẹ bọ́ sí apá kan kí n lè rí ààyè pa àwọn eniyan náà run ní ìṣẹ́jú kan.”


Kí ó mú àwo turari àwọn ọkunrin tí wọ́n kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí ó fi wọ́n rọ àwo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ìbòrí pẹpẹ, nítorí níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti mú wọn wá siwaju OLUWA, wọ́n ti di mímọ́. Èyí yóo sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.”


Èyí sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe ọmọ Aaroni kò gbọdọ̀ wá siwaju pẹpẹ OLUWA láti sun turari, kí ẹni náà má baà dàbí Kora ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti rán Mose pé kí ó sọ fún Eleasari.


Mose sì ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.


Kí o kó wọn sílẹ̀ níwájú Àpótí Ẹ̀rí ninu Àgọ́ Àjọ mi, níbi tí mo ti máa ń pàdé rẹ.


Mose kó àwọn ọ̀pá náà jáde kúrò níwájú OLUWA, ó kó wọn wá siwaju àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn wò wọ́n, olukuluku àwọn olórí sì mú ọ̀pá tirẹ̀.


Mose lọ mú ọ̀pá náà níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.


“Ẹ má jẹ́ kí ìdílé Kohati parun láàrin ẹ̀yà Lefi,


Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe kùn bí àwọn mìíràn ninu wọn ṣe kùn, tí Apani sì pa wọ́n.


Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ. Nítorí irú èyí ni ibinu Ọlọrun fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọràn.


Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín, kò sí ìgbà kan tí ẹ kò ṣe orí kunkun sí OLUWA.


“Ẹ ranti, ẹ má sì ṣe gbàgbé, bí ẹ ti mú OLUWA Ọlọrun yín bínú ninu aṣálẹ̀, láti ọjọ́ tí ẹ ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti títí tí ẹ fi dé ibí yìí ni ẹ̀ ń ṣe oríkunkun sí OLUWA.


Níbẹ̀ ni pẹpẹ wúrà wà fún sísun turari, ati àpótí majẹmu tí a fi wúrà bò yíká. Ninu àpótí yìí ni apẹ wúrà kékeré kan wà tí wọ́n fi mana sí ninu, ati ọ̀pá Aaroni tí ó rúwé nígbà kan rí, ati àwọn wàláà òkúta tí a kọ òfin mẹ́wàá sí.


Aláìníláárí ẹ̀dá ni àwọn ọmọ Eli mejeeji. Wọn kò bọ̀wọ̀ fún OLUWA rárá.


Àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan burúkú ati òǹrorò láàrin àwọn tí wọ́n bá Dafidi lọ ní, “Nítorí pé wọn kò bá wa lọ, a kò ní fún wọn ninu ìkógun wa tí a gbà pada, àfi aya ati àwọn ọmọ wọn nìkan ni wọ́n lè gbà.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan