Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 16:7 - Yoruba Bible

7 kí ẹ fi iná sinu wọn, kí ẹ sì gbé wọn lọ siwaju OLUWA. Ẹni tí OLUWA bá yàn ni yóo jẹ́ ẹni mímọ́; ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí kọjá ààyè yín, ẹ̀yin ọmọ Lefi!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Ki ẹ si fi iná sinu wọn, ki ẹ si fi turari sinu wọn niwaju OLUWA li ọla: yio si ṣe, ọkunrin ti OLUWA ba yàn, on ni ẹni mimọ́: o tó gẹ, ẹnyin ọmọ Lefi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Kí ẹ sì fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀ lọ́la níwájú Olúwa, yóò sì ṣe, ọkùnrin tí Olúwa bá yàn òun ni. Ẹ̀yin ọmọ Lefi, ẹ ti kọjá ààyè yín!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 16:7
10 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí wọ́n ṣe ìlara sí Mose ninu ibùdó, ati sí Aaroni, ẹni mímọ́ OLÚWA.


Wọ́n dojú kọ Mose ati Aaroni, wọ́n ní, “Ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí kọjá ààyè yín, nítorí pé olukuluku àwọn ọmọ Israẹli ni ó jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, OLUWA sì ń bẹ láàrin wọn. Kí ló dé tí ẹ̀yin gbé ara yín ga ju gbogbo àwọn eniyan OLUWA lọ?”


Ó sì sọ fún Kora ati àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ní ọ̀la OLUWA yóo fi ẹni tí í ṣe tirẹ̀ tí ó jẹ́ ẹni mímọ́ hàn. Ẹni tí OLUWA bá sì yàn ni yóo mú kí ó súnmọ́ òun.


Ní ọ̀la ìwọ ati àwọn ẹgbẹ́ rẹ, ẹ mú àwo turari,


Mose bá kọjú sí Kora, ó ní: “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọmọ Lefi!


Òun ni ó yàn wá nípasẹ̀ Kristi kí ó tó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀. Ó yàn wá kí á lè jẹ́ ẹni tí a yà sọ́tọ̀, tí kò ní àléébù níwájú rẹ̀, tí ó sì kún fún ìfẹ́.


Ṣugbọn ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí yín, ẹ̀yin ará, àyànfẹ́ Oluwa, nítorí Ọlọrun ti yàn yín láti ìbẹ̀rẹ̀ wá láti gbà yín là nípa Ẹ̀mí tí ó sọ yín di mímọ́, ati nípa gbígba òtítọ́ gbọ́.


Ṣugbọn ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun yàn, alufaa ọlọ́lá, ẹ̀yà mímọ́, eniyan tí Ọlọrun ṣe ní tirẹ̀, kí ẹ lè sọ àwọn iṣẹ́ ńlá tí ẹni tí ó pè yín láti inú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó yani lẹ́nu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan