Bí wọ́n ti ń pa àwọn eniyan, tí èmi nìkan dá dúró, mo dojúbolẹ̀, mo kígbe. Mo ní, “Áà! OLUWA Ọlọrun, ṣé o óo pa gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Israẹli nítorí pé ò ń bínú sí Jerusalẹmu ni?”
Ó sì sọ fún Kora ati àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ní ọ̀la OLUWA yóo fi ẹni tí í ṣe tirẹ̀ tí ó jẹ́ ẹni mímọ́ hàn. Ẹni tí OLUWA bá sì yàn ni yóo mú kí ó súnmọ́ òun.