Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 16:2 - Yoruba Bible

2 wọ́n kó aadọtaleerugba (250) ọkunrin tí wọ́n jọ jẹ́ olórí ati olókìkí ninu àwọn ọmọ Israẹli sòdí láti dìtẹ̀ mọ́ Mose.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Nwọn si dide niwaju Mose, pẹlu ãdọtalerugba ọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, ijoye ninu ijọ, awọn olorukọ ninu ajọ, awọn ọkunrin olokikí:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Wọ́n sì dìde sí Mose, pẹ̀lú àádọ́tà-lé-nígba (250) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli, ìjòyè nínú ìjọ, àwọn olórúkọ nínú àjọ, àwọn ọkùnrin olókìkí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 16:2
10 Iomraidhean Croise  

Àwọn òmìrán wà láyé ní ayé ìgbà náà, wọ́n tilẹ̀ tún wà láyé fún àkókò kan lẹ́yìn rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọkunrin Ọlọrun fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọ eniyan, àwọn ọmọ tí wọ́n bí ni àwọn òmìrán wọnyi. Àwọn ni wọ́n jẹ́ akọni ati olókìkí nígbà náà.


Láti inú ẹ̀yà Efuraimu, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹrin (20,800) akikanju ati alágbára, tí wọ́n jẹ́ olókìkí ninu ìdílé wọn ni wọ́n wá.


Àwọn Olórí ìdílé wọn nìwọ̀nyí: Eferi, Iṣi, Elieli, ati Asirieli; Jeremaya, Hodafaya ati Jahidieli, akikanju jagunjagun ni wọ́n, wọ́n sì jẹ́ olókìkí ati olórí ní ilé baba wọn.


Òkìkí ẹwà rẹ wá kàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè; o dára nítorí pé èmi ni mo fún ọ ní ẹwà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.


Wọ́n tú aṣọ lára rẹ̀, wọ́n kó àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin; wọ́n sì fi idà pa òun alára. Orúkọ rẹ̀ wá di yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn obinrin nígbà tí ìdájọ́ dé bá a.


Àwọn ni olórí tí a yàn ninu àwọn ọmọ Israẹli, olukuluku wọn jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà wọn, ati ní ìdílé wọn.


Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ̀ òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ ọmọbinrin ará Kuṣi ní iyawo.


OLUWA sì rán iná láti run àwọn aadọtaleerugba (250) ọkunrin tí wọn mú àwo turari wá siwaju Àgọ́ Àjọ.


Eliabu bí Nemueli, Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu yìí ni wọ́n jẹ́ olókìkí eniyan láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ni wọ́n bá Mose ati Aaroni ṣe gbolohun asọ̀ nígbà tí Kora dìtẹ̀, tí wọ́n tako OLUWA.


“Baba wa kú sinu aṣálẹ̀ láìní ọmọkunrin kankan. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí OLÚWA, ṣugbọn ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ ni.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan