Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 16:12 - Yoruba Bible

12 Mose bá ranṣẹ lọ pe Datani ati Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ṣugbọn wọ́n kọ̀ wọn kò wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Mose si ranṣẹ pè Datani ati Abiramu, awọn ọmọ Eliabu: nwọn si wipe, Awa ki yio gòke wá:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Mose sì ránṣẹ́ sí Datani àti Abiramu àwọn ọmọ Eliabu. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé “Àwa kò ní í wá!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 16:12
7 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí ọlọ́gbọ́n bá pe òmùgọ̀ lẹ́jọ́, ẹ̀rín ni òmùgọ̀ yóo máa fi rín, yóo máa pariwo, kò sì ní dákẹ́.


Àwọn eniyan náà yóo máa fìyà jẹ ara wọn, olukuluku yóo máa fìyà jẹ ẹnìkejì rẹ̀, àwọn aládùúgbò yóo sì máa fìyà jẹ ara wọn. Ọmọde yóo nàró mọ́ àgbàlagbà, àwọn mẹ̀kúnnù yóo máa dìde sí àwọn ọlọ́lá.


Kora ọmọ Iṣari láti inú ìdílé Kohati ọmọ Lefi, pẹlu Datani ati Abiramu àwọn ọmọ Eliabu, pẹlu Ooni ọmọ Peleti láti inú ẹ̀yà Reubẹni gbìmọ̀ pọ̀,


Ṣé ẹ kò mọ̀ pé OLUWA ni ìwọ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí, nígbà tí ẹ̀ ń fi ẹ̀sùn kan Aaroni? Ta ni Aaroni tí ẹ̀yin ń fi ẹ̀sùn kàn?”


Wọ́n ní, “O mú wa wá láti ilẹ̀ ọlọ́ràá Ijipti tí ó kún fún wàrà ati fún oyin, o fẹ́ wá pa wá sinu aṣálẹ̀ yìí, sibẹ kò tó ọ, o tún fẹ́ sọ ara rẹ di ọba lórí gbogbo wa.


Bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí fún àwọn eniyan wọnyi lónìí. Àlá tí wọn ń lá, fún ìbàjẹ́ ara wọn ni. Wọ́n tàpá sí àwọn aláṣẹ. Wọ́n ń sọ ìsọkúsọ sí àwọn ẹ̀dá ọ̀run tí ó lógo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan