Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 16:11 - Yoruba Bible

11 Ṣé ẹ kò mọ̀ pé OLUWA ni ìwọ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí, nígbà tí ẹ̀ ń fi ẹ̀sùn kan Aaroni? Ta ni Aaroni tí ẹ̀yin ń fi ẹ̀sùn kàn?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Nitorina, iwọ ati gbogbo ẹgbẹ rẹ kójọ pọ̀ si OLUWA: ati kini Aaroni, ti ẹnyin nkùn si i?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Olúwa ni ìwọ àti gbogbo ẹlẹgbẹ́ rẹ takò. Ta a ni Aaroni jẹ́ tí ẹ̀yin ó fi kùn sí i?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 16:11
15 Iomraidhean Croise  

Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn aṣọ́nà láti inú ìran Kora ati ti Merari.


Nígbà tí wọ́n ṣe ìlara sí Mose ninu ibùdó, ati sí Aaroni, ẹni mímọ́ OLÚWA.


Wọ́n bá ka ẹ̀sùn sí Mose lẹ́sẹ̀, wọ́n ní, “Fún wa ní omi tí a óo mu.” Mose dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ka ẹ̀sùn sí mi lẹ́sẹ̀? Kí ló dé tí ẹ sì fi ń dán OLUWA wò?”


Nígbà tí ó yá àwọn eniyan náà bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí OLUWA nípa ìṣòro wọn. Nígbà tí OLUWA gbọ́ kíkùn wọn, inú bí i, ó sì fi iná jó wọn; iná náà run gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní òpin ibùdó náà.


Mose bá ranṣẹ lọ pe Datani ati Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ṣugbọn wọ́n kọ̀ wọn kò wá.


Wọ́n dojú kọ Mose ati Aaroni, wọ́n ní, “Ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí kọjá ààyè yín, nítorí pé olukuluku àwọn ọmọ Israẹli ni ó jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, OLUWA sì ń bẹ láàrin wọn. Kí ló dé tí ẹ̀yin gbé ara yín ga ju gbogbo àwọn eniyan OLUWA lọ?”


“Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá kọ̀ yín èmi ni ó kọ̀. Ẹni tí ó bá sì wá kọ̀ mí, ó kọ ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi.”


Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán níṣẹ́, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.”


Kí o tó ta ilẹ̀ náà, mo ṣebí tìrẹ ni? Nígbà tí o tà á tán, mo ṣebí o ní àṣẹ lórí owó tí o tà á? Kí ló dé tí o gbèrò irú nǹkan yìí? Kì í ṣe eniyan ni o ṣèké sí, Ọlọrun ni.”


Nítorí náà, ẹni tí ó bá fojú di aláṣẹ ń tàpá sí àṣẹ Ọlọrun. Àwọn tí ó bá sì ṣe àfojúdi yóo forí ara wọn gba ìdájọ́.


Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe kùn bí àwọn mìíràn ninu wọn ṣe kùn, tí Apani sì pa wọ́n.


Nítorí ta ni Apolo? Ta ni Paulu? Ṣebí iranṣẹ ni wọ́n, tí ẹ ti ipasẹ̀ wọn di onigbagbọ? Olukuluku wọn jẹ́ iṣẹ́ tirẹ̀ bí Ọlọrun ti rán an.


Àwọn wọnyi ni àwọn tí wọn ń kùn ṣá, nǹkan kì í fi ìgbà kan tẹ́ wọn lọ́rùn. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn ni wọ́n ń lépa. Ẹnu wọn gba ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà. Kò sí ohun tí wọn kò lè ṣe láti rí ohun tí wọ́n fẹ́. Wọn á máa wá ojú rere àwọn tí wọ́n bá lè rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn.


OLUWA dá Samuẹli lóhùn, ó ní, “Gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn eniyan náà wí fún ọ, nítorí pé kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, èmi ni wọ́n kọ̀ lọ́ba.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan