Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 15:9 - Yoruba Bible

9 ẹ óo mú ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdajì òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò wá,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Nigbana ni ki o mu wá pẹlu ẹgbọrọ akọmalu na, ẹbọ ohunjijẹ idamẹwa mẹta òṣuwọn iyẹfun ti a fi àbọ òsuwọn hini oróro pò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ẹni náà yóò mú ọ̀dọ́ akọ màlúù náà wá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdajì òṣùwọ̀n òróró pò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 15:9
18 Iomraidhean Croise  

Onani dá Dafidi lóhùn pé, “olúwa mi, mú gbogbo rẹ̀, kí o sì ṣe ohun tí o bá fẹ́ níbẹ̀. Wò ó, mo tún fún ọ ní àwọn akọ mààlúù yìí fún ẹbọ sísun, ati pákó ìpakà fún dídá iná ẹbọ sísun, ati ọkà fún ẹbọ ohun jíjẹ. Mo bùn ọ́ ní gbogbo rẹ̀.”


A óo máa pèsè burẹdi ìfihàn ati ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo, ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ẹbọ ọjọ́ ìsinmi, ati ti oṣù tuntun fún àwọn àsè tí wọ́n ti là sílẹ̀, ati fún gbogbo ohun mímọ́, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli kúrò, ati fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọrun wa.


Lẹ́yìn náà, ọkunrin náà wí fún mi pé, “Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ ìhà àríwá ati àwọn yàrá ìhà gúsù tí wọ́n kọjú sí àgbàlá ni àwọn yàrá mímọ́. Níbẹ̀ ni àwọn alufaa tí ń rú ẹbọ sí OLUWA yóo ti máa jẹ ẹbọ mímọ́ jùlọ. Níbẹ̀ ni wọn yóo máa kó àwọn ẹbọ mímọ́ jùlọ sí; ati àwọn ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, nítorí ibẹ̀ jẹ́ ibi mímọ́.


Ní ọjọ́ àsè ati ìgbà àjọ̀dún, ìwọ̀n eefa ọkà kan ni wọn óo fi rúbọ pẹlu ọ̀dọ́ mààlúù kan, ìwọ̀n eefa ọkà kan pẹlu àgbò kan, ati ìwọ̀n eefa ọkà tí eniyan bá lágbára pẹlu ọ̀dọ́ aguntan, ṣugbọn ó gbọdọ̀ fi ìwọ̀n òróró hini kọ̀ọ̀kan ti ìwọ̀n eefa ọkà kọ̀ọ̀kan.


Bẹ́ẹ̀ ni wọn óo ṣe máa pèsè aguntan ati ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró láràárọ̀, fún ẹbọ ọrẹ sísun ìgbà gbogbo.”


Ẹbọ ọkà pẹlu àgbò yóo jẹ́ ìwọ̀n eefa kan. Ìwọ̀n ọkà pẹlu iye ọ̀dọ́ aguntan tí ó bá lágbára ni yóo fi rú ẹbọ ọkà pẹlu ọ̀dọ́ aguntan. Ṣugbọn ó gbọdọ̀ fi òróró hini kọ̀ọ̀kan ti eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan.


Fún ẹbọ ohun jíjẹ, yóo tọ́jú ìwọ̀n eefa ọkà kan fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, ati eefa ọkà kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan ati ìwọ̀n ọkà tí ó bá ti lágbára fún àwọn àgbò, yóo fi hini òróró kọ̀ọ̀kan ti eefa ọkà kọ̀ọ̀kan.


A ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ti ohun mímu dúró ní ilé OLUWA, àwọn alufaa tíí ṣe iranṣẹ OLUWA ń ṣọ̀fọ̀.


Ó ṣeéṣe kí Ọlọrun ṣàánú, kí ó yí ibinu rẹ̀ pada, kí ó sì tú ibukun rẹ̀ sílẹ̀, kí ẹ lè rú ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu fún OLUWA Ọlọrun yín.


“Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo mú ọ̀dọ́ àgbò meji tí kò lábàwọ́n, ati ọ̀dọ́ abo aguntan ọlọ́dún kan tí kò lábàwọ́n, ati ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a fi òróró pò ati ìwọ̀n ìgò òróró kan fún ẹbọ ohun jíjẹ.


“Èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ẹbọ ohun jíjẹ. Àwọn ọmọ Aaroni ni yóo máa rúbọ náà níwájú pẹpẹ, níwájú OLUWA.


Òfin ẹbọ sísun ni, ati ti ẹbọ ohun jíjẹ, ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, ti ẹbọ ìyàsímímọ́, ati ti ẹbọ alaafia;


pẹlu ìdajì òṣùnwọ̀n hini ọtí waini kan, fún ẹbọ ohun mímu, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun. Yóo jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA.


Bí ẹ bá mú akọ mààlúù wá fún ọrẹ ẹbọ sísun, tabi fún ìrúbọ láti san ẹ̀jẹ́ tabi fún ẹbọ alaafia sí OLUWA,


Fún ẹbọ ohun jíjẹ, ẹ lo ìdámẹ́wàá mẹta ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa, tí a fi òróró pò fún akọ mààlúù kan ati idamẹrin ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi òróró pò fún àgbò kan.


Kí ẹbọ ohun mímu jẹ́ ààbọ̀ òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún akọ mààlúù kan, ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún àgbò kan ati idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ọ̀dọ́ aguntan kan. Èyí ni ìlànà ẹbọ sísun ti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù.


Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọjọ́ kinni oṣù, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ pẹlu ẹbọ ohun mímu ojoojumọ, gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.


Nígbà tí ó gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó mú un lọ́wọ́ lọ sí Ṣilo. Nígbà tí ó ń lọ, ó mú akọ mààlúù ọlọ́dún mẹta kan lọ́wọ́, ati ìyẹ̀fun ìwọ̀n efa kan, ati ọtí waini ẹ̀kún ìgò aláwọ kan. Ó sì mú Samuẹli lọ sí Ṣilo ní ilé OLUWA, ọmọde ni Samuẹli nígbà náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan