Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 15:8 - Yoruba Bible

8 Bí ẹ bá mú akọ mààlúù wá fún ọrẹ ẹbọ sísun, tabi fún ìrúbọ láti san ẹ̀jẹ́ tabi fún ẹbọ alaafia sí OLUWA,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Bi iwọ ba si pèse ẹgbọrọ akọmalu kan fun ẹbọ sisun, tabi fun ẹbọ kan, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ alafia si OLUWA:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 “ ‘Nígbà tí ẹ bá sì pèsè ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ọrẹ tàbí ẹbọ sísun, láti fi san ẹ̀jẹ́ tàbí fún ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 15:8
10 Iomraidhean Croise  

“Bí ó bá jẹ́ pé láti inú agbo mààlúù ni ó ti mú un láti fi rú ẹbọ sísun, akọ mààlúù tí kò ní àbààwọ́n ni kí ó mú wá, kí ó mú un wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi rúbọ, kí ó lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLUWA.


Ṣugbọn ẹni tí ó wá rúbọ yóo fi omi fọ àwọn nǹkan inú ẹran náà ati ẹsẹ̀ rẹ̀, alufaa yóo sì sun gbogbo rẹ̀ níná lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun, ẹbọ tí a fi iná sun, tí ó jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.


Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia sí OLUWA láti san ẹ̀jẹ́, tabi fún ọrẹ àtinúwá; kì báà jẹ́ láti inú agbo mààlúù tabi láti inú agbo aguntan ni yóo ti mú ẹran ìrúbọ yìí, ó níláti jẹ́ pípé, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kan lára, kí ẹbọ náà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.


“Bí ẹnìkan bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia, tí ó sì mú ẹran láti inú agbo ẹran rẹ̀ fún ẹbọ náà, kì báà jẹ́ akọ tabi abo, ó níláti jẹ́ èyí tí kò ní àbààwọ́n níwájú OLUWA.


Àwọn ọmọ Aaroni yóo sun wọ́n lórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ; ẹbọ sísun ni, tí ó ní òórùn dídùn, tí inú OLUWA sì dùn sí.


bí gbogbo ìjọ eniyan Israẹli bá ṣẹ̀, láìmọ̀, wọn óo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan rú ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà.


pẹlu ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini ọtí fún ẹbọ ohun mímu; yóo jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA.


ẹ óo mú ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdajì òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò wá,


Kí wọ́n mú akọ mààlúù kékeré kan ati ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ wá. Kí wọ́n sì mú akọ mààlúù kékeré mìíràn wá, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan