Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 15:7 - Yoruba Bible

7 pẹlu ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini ọtí fún ẹbọ ohun mímu; yóo jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Ati fun ẹbọ ohunmimu, ki iwọ ki o mú idamẹta òṣuwọn hini ọti-waini wá, fun õrùn didùn si OLUWA.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Àti ìdákan nínú mẹ́ta òṣùwọ̀n wáìnì fún ọrẹ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 15:7
8 Iomraidhean Croise  

Ní ọjọ́ keji, wọ́n fi ẹgbẹrun akọ mààlúù rú ẹbọ sísun sí OLUWA, ati ẹgbẹrun àgbò, ati ẹgbẹrun ọ̀dọ́ aguntan, pẹlu ọrẹ ohun mímu ati ọpọlọpọ ẹbọ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.


Ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a pò pọ̀ mọ́ idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ojúlówó epo olifi, ni kí o fi rúbọ pẹlu àgbò kinni, pẹlu idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ìtasílẹ̀.


Fún ẹbọ àgbò, yóo wá ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò wá,


Bí ẹ bá mú akọ mààlúù wá fún ọrẹ ẹbọ sísun, tabi fún ìrúbọ láti san ẹ̀jẹ́ tabi fún ẹbọ alaafia sí OLUWA,


pé kí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn máa mú ọrẹ wá fún ohun ìrúbọ sí òun OLUWA ní àkókò rẹ̀, ati àwọn nǹkan tí wọn yóo máa fi rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn.


Ẹbọ ohun mímu rẹ̀ yóo máa jẹ́ idamẹrin òṣùnwọ̀n hini fún ọ̀dọ́ aguntan kan. O óo sì ta ọtí líle náà sílẹ̀ lẹ́bàá pẹpẹ ìrúbọ bí ẹbọ sí OLUWA.


pẹlu burẹdi agbọ̀n kan, tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati burẹdi aládùn tí a fi ìyẹ̀fun dáradára, tí a fi òróró pò ṣe, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà ninu, tí a ta òróró sí lórí, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ti ohun mímu.


Ṣugbọn igi àjàrà dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí ń pa ọtí mi, tí ń mú inú àwọn oriṣa ati àwọn eniyan dùn tì, kí n wá jọba lórí ẹ̀yin igi?’


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan