Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 15:5 - Yoruba Bible

5 ati idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí fún ẹbọ ohun mímu, pẹlu ẹbọ sísun tabi ẹbọ ọ̀dọ́ aguntan kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Ati idamẹrin òṣuwọn hini ọti-waini fun ẹbọ ohunmimu ni ki iwọ ki o pèse pẹlu ẹbọ sisun, tabi ẹbọ, fun ọdọ-agutan kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan yálà fún ọrẹ tàbí ẹbọ sísun ni, kí ẹ pèsè ìdámẹ́rin òṣùwọ̀n wáìnì gẹ́gẹ́ bí ohun mímu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 15:5
18 Iomraidhean Croise  

Yàtọ̀ sí ọpọlọpọ ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀rá rú ẹbọ alaafia ati ẹbọ ohun mímu fún ẹbọ sísun. Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ìsìn ninu ilé OLUWA ṣe tún bẹ̀rẹ̀.


“Ṣíṣọ́ ni kí o ṣọ́ owó yìí ná: fi ra akọ mààlúù, àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan ati èròjà ẹbọ ohun jíjẹ ati ohun mímu, kí o fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ Tẹmpili Ọlọrun rẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu.


N óo mu ẹbọ nǹkan mímu wá fún OLUWA, n óo sì pe orúkọ rẹ̀.


Ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a pò pọ̀ mọ́ idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ojúlówó epo olifi, ni kí o fi rúbọ pẹlu àgbò kinni, pẹlu idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ìtasílẹ̀.


Fà mí mọ́ra, jẹ́ kí á ṣe kíá, ọba ti mú mi wọ yàrá rẹ̀. Inú wa yóo máa dùn, a óo sì máa yọ̀ nítorí rẹ a óo gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí waini lọ; abájọ tí gbogbo àwọn obinrin ṣe fẹ́ràn rẹ!


“Bí ó bá jẹ́ pé láti inú agbo aguntan tabi agbo ewúrẹ́ ni ó ti mú ẹran fún ẹbọ sísun rẹ̀, akọ tí kò ní àbààwọ́n ni kí ó mú.


Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo rú pẹlu rẹ̀ nìyí: ìdámárùn-ún ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí wọ́n fi òróró pò, ẹ óo fi rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA, kí ẹ sì fi idamẹrin ìwọ̀n hini ọtí waini rú ẹbọ ohun mímu pẹlu rẹ̀.


“Bí ó bá jẹ́ pé aguntan tabi ewúrẹ́ ni yóo mú láti inú agbo ẹran rẹ̀ láti fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, kì báà jẹ́ akọ tabi abo ẹran, ó gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí kò ní àbààwọ́n.


Bí ó bá jẹ́ ọ̀dọ́ aguntan ni yóo fi rúbọ, kí ó mú un wá siwaju OLUWA,


Báwo ni ilẹ̀ náà yóo ti dára tó, yóo sì ti lẹ́wà tó? Ọkà yóo sọ àwọn ọdọmọkunrin di alágbára ọtí waini titun yóo sì fún àwọn ọdọmọbinrin ní okun.


“Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe pẹlu akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan tabi àgbò kọ̀ọ̀kan tabi ọ̀dọ́ àgbò kọ̀ọ̀kan tabi ọmọ aguntan kọ̀ọ̀kan.


Fún ẹbọ àgbò, yóo wá ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò wá,


Kí ẹbọ ohun mímu jẹ́ ààbọ̀ òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún akọ mààlúù kan, ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún àgbò kan ati idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ọ̀dọ́ aguntan kan. Èyí ni ìlànà ẹbọ sísun ti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù.


Ẹbọ ohun mímu rẹ̀ yóo máa jẹ́ idamẹrin òṣùnwọ̀n hini fún ọ̀dọ́ aguntan kan. O óo sì ta ọtí líle náà sílẹ̀ lẹ́bàá pẹpẹ ìrúbọ bí ẹbọ sí OLUWA.


Ṣugbọn bí a bá fi mí ṣe ohun ìrúbọ ati ohun èèlò ninu ìsìn nítorí igbagbọ yín, ó dùn mọ́ mi, n óo sì máa yọ̀ pẹlu gbogbo yín.


Ní tèmi, a ti fi mí rúbọ ná. Àkókò ati fi ayé sílẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tó.


Ṣugbọn igi àjàrà dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí ń pa ọtí mi, tí ń mú inú àwọn oriṣa ati àwọn eniyan dùn tì, kí n wá jọba lórí ẹ̀yin igi?’


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan