Numeri 15:4 - Yoruba Bible4 ẹni tí ó fẹ́ rúbọ yóo tọ́jú ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi idamẹrin òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò fún ẹbọ ohun jíjẹ; Faic an caibideilBibeli Mimọ4 Nigbana ni ki ẹniti nru ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ na si OLUWA ki o mú ẹbọ ohunjijẹ wá, idamẹwa òṣuwọn iyẹfun ti a fi idamẹrin òṣuwọn hini oróro pò: Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní4 nígbà náà ni kí ẹni tí ó bá mú ọrẹ rẹ̀ wá, yóò tún mú ẹbọ ohun jíjẹ ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná pẹ̀lú ìdámẹ́rin òṣùwọ̀n òróró wá síwájú Olúwa. Faic an caibideil |
Wọn óo sì kó gbogbo àwọn ará yín bọ̀ láti orílẹ̀-èdè gbogbo, wọn óo kó wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA. Wọn óo máa bọ̀ lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́-ogun, lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí, wọn óo máa wá sí ìlú Jerusalẹmu, òkè mímọ́ mi, bí àwọn ọmọ Israẹli yóo ti máa mú ẹbọ ohun jíjẹ wọn wá sí ilé OLUWA, ninu àwo tí ó mọ́.