Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 15:3 - Yoruba Bible

3 tí ẹ bá mú ninu agbo ẹran yín láti fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA tabi láti fi san ẹ̀jẹ́, tabi láti fi rú ẹbọ àtinúwá, tabi ẹbọ ní ọjọ́ àjọ yín, láti pèsè òórùn dídùn fún OLUWA;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ti ẹnyin o ba si ṣe ẹbọ iná si OLUWA, ẹbọ sisun, tabi ẹbọ, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwá, tabi ninu ajọ nyin lati ṣe õrùn didùn si OLUWA ninu agbo-ẹran, tabi ọwọ́-ẹran:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 tí ẹ̀yin ó bá sì ṣe ẹbọ iná sí Olúwa ẹbọ sísun, tàbí ẹbọ, láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí ọrẹ àtinúwá, tàbí nínú àjọ yín, láti ṣe òórùn dídùn sí Olúwa nínú agbo ẹran tàbí ọ̀wọ́ ẹran,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 15:3
27 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí OLUWA gbọ́ òórùn dídùn ẹbọ náà, ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “N kò ní fi ilẹ̀ gégùn-ún mọ́ nítorí eniyan, nítorí pé, láti ìgbà èwe wọn wá ni èrò inú wọn ti jẹ́ kìkì ibi. Bẹ́ẹ̀ ni n kò ní pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run mọ́ bí mo ti ṣe yìí.


“Ṣíṣọ́ ni kí o ṣọ́ owó yìí ná: fi ra akọ mààlúù, àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan ati èròjà ẹbọ ohun jíjẹ ati ohun mímu, kí o fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ Tẹmpili Ọlọrun rẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu.


N óo rú ẹbọ ọrẹ àtinúwá sí ọ, n óo máa yin orúkọ rẹ, OLUWA, nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀.


kí o sì sun gbogbo wọn lórí pẹpẹ, ẹbọ sísun olóòórùn dídùn ni sí OLUWA, àní ẹbọ tí a fi iná sun.


Lẹ́yìn náà, gba gbogbo àkàrà náà lọ́wọ́ wọn, kí o fi iná sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹlu ẹbọ sísun olóòórùn dídùn níwájú OLUWA, ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA ni.


Àṣaálẹ́ ni kí o fi ọ̀dọ́ aguntan keji rúbọ, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ọtí waini fún ìtasílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti òwúrọ̀. Ẹbọ olóòórùn dídùn ni, àní ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA.


Ibi mímọ́ ni kí ẹ ti jẹ ẹ́, nítorí pé òun ni ìpín yín ati ti àwọn ọmọ yín, ninu ẹbọ sísun OLUWA, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni OLUWA pa á láṣẹ fún mi.


pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí ẹnìkan bá jẹ́jẹ̀ẹ́ pataki kan láti fi odidi eniyan fún OLUWA, tí kò bá lè mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ, iye tí ó níláti san nìyí:


“Ṣugbọn bí ẹbọ ọrẹ rẹ̀ bá jẹ́ ti ẹ̀jẹ́ tabi ọrẹ àtinúwá, wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà, ṣugbọn bí ó bá ṣẹ́kù, wọ́n lè jẹ ẹ́ ní ọjọ́ keji;


Kí ẹ fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji, ati àgbò kan, ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.


Kí ẹ fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù kan, ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.


pẹlu burẹdi agbọ̀n kan, tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati burẹdi aládùn tí a fi ìyẹ̀fun dáradára, tí a fi òróró pò ṣe, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà ninu, tí a ta òróró sí lórí, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ti ohun mímu.


Ohùn kan láti ọ̀run wá sọ pé, “Àyànfẹ́ ọmọ mi nìyí, inú mi dùn sí i gidigidi.”


Nítorí àwa ni òórùn dídùn tí Kristi fi rúbọ sí Ọlọrun lọ́dọ̀ àwọn tí à ń gbàlà ati àwọn tí ń ṣègbé.


Fún àwọn tí wọn ń ṣègbé, a dàbí òórùn tí n pani, ṣugbọn fún àwọn tí à ń gbàlà, a dàbí òórùn dídùn tí ó ń fún wọn ní ìyè. Ta ló tó ṣe irú iṣẹ́ yìí?


Ẹ máa rìn ninu ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ wa, tí ó fi ara òun tìkararẹ̀ rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí Ọlọrun nítorí tiwa.


ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn láti fi ibùgbé rẹ̀ sí nígbà náà, ni kí ẹ kó gbogbo àwọn nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín wa, ẹbọ sísun yín ati àwọn ẹbọ mìíràn, ìdámẹ́wàá yín, ati ọrẹ, ati gbogbo ẹ̀jẹ́ yín tí ẹ bá jẹ́ fún OLUWA.


Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu ohun tí o bá jẹ́ ìdámẹ́wàá yín ninu ìlú yín, kì báà ṣe ìdámẹ́wàá ọkà yín, tabi ti ọtí waini, tabi ti òróró, tabi ti àkọ́bí mààlúù, tabi ti ewúrẹ́, tabi ti aguntan, tabi ohunkohun tí ẹ bá fi san ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, tabi ọrẹ àtinúwá yín tabi ọrẹ àkànṣe yín.


Ibẹ̀ ni kí ẹ máa mú gbogbo ẹbọ sísun yín, ati àwọn ẹbọ yòókù wá, ati ìdámẹ́wàá yín, ati ọrẹ àtinúwá yín, ati ẹ̀jẹ́ yín tí ẹ bá jẹ́ fún OLUWA, ati àkọ́bí mààlúù yín, ati ti aguntan yín.


Ìwé ẹ̀rí nìyí fún ohun gbogbo tí ẹ fún mi, ó tilẹ̀ ti pọ̀jù. Mo ní ànító nígbà tí mo rí ohun tí ẹ fi rán Epafiroditu sí mi gbà. Ó dàbí òróró olóòórùn dídùn, bí ẹbọ tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà, tí inú Ọlọrun dùn sí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan