Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 15:16 - Yoruba Bible

16 Òfin ati ìlànà kan náà ni yóo wà fún ẹ̀yin ati àjèjì tí ń gbé pẹlu yín.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Ofin kan ati ìlana kan ni ki o wà fun nyin, ati fun alejò ti nṣe atipo lọdọ nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Òfin kan àti ìlànà kan ni yóò wà fún yín àti fún àwọn àlejò tí ń gbé láàrín yín.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 15:16
8 Iomraidhean Croise  

“Bákan náà, nígbà tí àlejò kan, tí kì í ṣe ọmọ Israẹli, bá wá láti ilẹ̀ òkèèrè nítorí orúkọ rẹ,


Ati ẹ̀yin, ati àlejò tí ń gbé ààrin yín, òfin kan ṣoṣo ni ó de gbogbo yín.”


Òfin kan náà tí ó de àlejò, ni ó gbọdọ̀ de onílé, nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”


“Bí ẹnìkan lásán ninu àwọn eniyan náà bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣe ọ̀kan ninu àwọn ohun tí OLUWA ti pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, tí ó sì jẹ̀bi,


OLUWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé,


Wọn yóo jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn ọmọ Israẹli tabi àwọn àlejò tí ó wà láàrin wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ sibẹ.


“Bí àlejò kan bá wà ní ààrin yín tí ó sì fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá, yóo ṣe é gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀. Òfin ati ìlànà kan náà ni ó wà fún gbogbo yín, ati onílé ati àlejò.”


Gbogbo Israẹli, ati onílé, ati àlejò, gbogbo àwọn àgbààgbà, ati àwọn olórí, ati àwọn aṣiwaju dúró ní òdìkejì Àpótí Majẹmu OLUWA, níwájú àwọn alufaa, ọmọ Lefi, tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu náà. Ìdajì wọn dúró níwájú òkè Ebali bí Mose, iranṣẹ OLUWA, ti pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan