Ní ọjọ́ àsè ati ìgbà àjọ̀dún, ìwọ̀n eefa ọkà kan ni wọn óo fi rúbọ pẹlu ọ̀dọ́ mààlúù kan, ìwọ̀n eefa ọkà kan pẹlu àgbò kan, ati ìwọ̀n eefa ọkà tí eniyan bá lágbára pẹlu ọ̀dọ́ aguntan, ṣugbọn ó gbọdọ̀ fi ìwọ̀n òróró hini kọ̀ọ̀kan ti ìwọ̀n eefa ọkà kọ̀ọ̀kan.
pẹlu burẹdi agbọ̀n kan, tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati burẹdi aládùn tí a fi ìyẹ̀fun dáradára, tí a fi òróró pò ṣe, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà ninu, tí a ta òróró sí lórí, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ti ohun mímu.