Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 13:21 - Yoruba Bible

21 Àwọn eniyan náà lọ, wọ́n sì wo ilẹ̀ náà láti aṣálẹ̀ Sini títí dé Rehobu ati ni ẹ̀bá ibodè Hamati.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Bẹ̃ni nwọn gòke lọ, nwọn si ṣe amí ilẹ na lati ijù Sini lọ dé Rehobu, ati lọ si Hamati.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti Aginjù Sini títí dé Rehobu lọ́nà Lebo-Hamati.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 13:21
15 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Toi ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti ṣẹgun gbogbo àwọn ọmọ ogun Hadadeseri,


Ohun tí OLUWA sọ nípa Damasku nìyí, Ó ní, “Ìdààmú dé bá Hamati ati Aripadi, nítorí pé wọ́n gbọ́ ìròyìn burúkú: Jìnnìjìnnì dà bò wọ́n, ọkàn wọn sì dàrú, bí omi òkun tí kò lè dákẹ́ jẹ́ẹ́.


Ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Kalidea tẹ Sedekaya ọba, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babiloni sì ṣe ìdájọ́ fún un.


àwọn ìlú Berota, Sibiraimu (tí ó wà ní ààlà Damasku ati Hamati), títí dé Haseri Hatikoni, tí ó wà ní ààlà Haurani.


Ẹ lọ wo ìlú Kane; ẹ ti ibẹ̀ lọ sí Hamati, ìlú ńlá nì, lẹ́yìn náà ẹ lọ sí ìlú Gati, ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Ṣé wọ́n sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yín lọ ni? Tabi agbègbè wọn tóbi ju tiyín lọ?


Ní oṣù kinni, àwọn ọmọ Israẹli dé aṣálẹ̀ Sini, wọ́n sì ṣe ibùdó wọn sí Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú sí, tí wọn sì sin ín sí.


nítorí o ṣàìgbọràn sí àṣẹ mi ninu aṣálẹ̀ Sini. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí mi ní Meriba, ẹ kọ̀ láti fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà.” (Meriba ni wọ́n ń pe àwọn omi tí ó wà ní Kadeṣi ní aṣálẹ̀ Sini).


Láti Esiongeberi wọ́n lọ sí aṣálẹ̀ Sini, tíí ṣe Kadeṣi.


Láti ibẹ̀ lọ dé ẹnu ibodè Hamati, títí dé Sedadi,


Wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí agbègbè olókè náà, títí tí wọ́n fi dé àfonífojì Eṣikolu, tí wọ́n sì ṣe amí rẹ̀.


Nítorí pé, ẹ̀yin mejeeji ni ẹ kò hùwà òtítọ́ sí mi láàrin àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí ẹ wà ní odò Meriba Kadeṣi, ní aṣálẹ̀ Sini. Ẹ tàbùkù mi lójú gbogbo àwọn eniyan, ẹ kò bọ̀wọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ níwájú àwọn eniyan náà.


ati ilẹ̀ àwọn ará Gebali, gbogbo Lẹbanoni ní apá ìlà oòrùn, láti Baaligadi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni títí dé ibodè Hamati.


Àpèjúwe ìpín tí ó kan ẹ̀yà Juda lára ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli gbà, tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn nìyí: Ilẹ̀ náà lọ títí dé apá ìhà gúsù, ní ààlà ilẹ̀ Edomu, títí dé aṣálẹ̀ Sini.


Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà wọ́n sílẹ̀, nítorí pé wọ́n jìnnà sí ìlú Sidoni, wọn kò sì bá ẹnikẹ́ni ní àyíká wọn da nǹkankan pọ̀. Àfonífojì Betirehobu ni ìlú Laiṣi yìí wà. Wọ́n tún un kọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan