Numeri 13:2 - Yoruba Bible2 “Rán amí lọ wo ilẹ̀ Kenaani tí mo fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó bá jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ni kí o rán.” Faic an caibideilBibeli Mimọ2 Rán enia, ki nwọn ki o si ṣe amí ilẹ Kenaani, ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli: ọkunrin kan ni ki ẹnyin ki o rán ninu ẹ̀ya awọn baba wọn, ki olukuluku ki o jẹ́ ijoye ninu wọn. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní2 “Rán ènìyàn díẹ̀ láti lọ yẹ ilẹ̀ Kenaani wò èyí tí mo ti fún àwọn ọmọ Israẹli. Rán ẹnìkọ̀ọ̀kan, tí ó jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.” Faic an caibideil |
Mo bá fi mú àwọn olórí olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, àwọn tí wọ́n gbọ́n tí wọ́n sì ní ìrírí, mo yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí fun yín. Mo fi àwọn kan jẹ balogun lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn lórí araadọta eniyan; bẹ́ẹ̀ ni mo fi àwọn ẹlòmíràn jẹ balogun lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá, mo sì fi àwọn kan ṣe olórí ninu gbogbo ẹ̀yà yín.