“Gbogbo yín wá sọ́dọ̀ mi, ẹ sì wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á rán àwọn eniyan lọ ṣiwaju wa, láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè wá jábọ̀ fún wa, kí á lè mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí á tọ̀, ati àwọn ìlú tí ó yẹ kí á wọ̀.’
Bákan náà ni ẹ ṣe ní Kadeṣi Banea, nígbà tí OLUWA ran yín lọ, tí ó ní kí ẹ lọ gba ilẹ̀ tí òun ti fi fun yín. Ẹ ṣe orí kunkun sí àṣẹ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò gbà á gbọ́, ẹ kò sì tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ẹni ogoji ọdún ni mí nígbà tí Mose iranṣẹ OLUWA rán mi láti Kadeṣi Banea láti ṣe amí ilẹ̀ náà. Bí ọkàn mi ti rí gan-an nígbà náà ni mo ṣe ròyìn fún un.
Lẹ́yìn náà, Joṣua ọmọ Nuni rán amí meji láti Akasia, lọ sí Jẹriko, ó ní, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá jùlọ, ìlú Jẹriko.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì dé sí ilé aṣẹ́wó kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rahabu.