Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 12:3 - Yoruba Bible

3 Mose ni ó jẹ́ oníwà ìrẹ̀lẹ̀ jù ninu gbogbo ẹni tí ó wà láyé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ṣugbọn ọkunrin na Mose, o ṣe ọlọkàn tutù jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 (Mose sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù ju gbogbo ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 12:3
16 Iomraidhean Croise  

OLUWA ní ń gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ró, òun ni ó sì ń sọ àwọn eniyan burúkú di ilẹ̀ẹ́lẹ̀.


Nítorí pé inú OLUWA dùn sí àwọn eniyan rẹ̀, a sì máa fi ìṣẹ́gun dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.


Lójijì, OLUWA sọ fún Mose, Aaroni, ati Miriamu pé, “Ẹ wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.”


Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onírẹ̀lẹ̀ ati ọlọ́kàn tútù ni mí, ọkàn yín yóo sì balẹ̀.


“Ẹ sọ fún ọdọmọbinrin, Sioni, pé, Wo ọba rẹ tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ; pẹlu ìrẹ̀lẹ̀, ó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ẹranko tí à ń lò láti rẹrù.”


Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀, nítorí wọn yóo jogún ayé.


Èmi Paulu fi ìrẹ̀lẹ̀ Kristi ati àánú rẹ̀ bẹ̀ yín, èmi tí ẹ̀ ń sọ pé nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín mo jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ṣugbọn nígbà tí mo bá kúrò lọ́dọ̀ yín mo di ògbójú si yín.


N kò rò pé mo kéré sí àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní “aposteli” pataki wọnyi!


Mo ti di aṣiwèrè! Ẹ̀yin ni ẹ sì sọ mí dà bẹ́ẹ̀. Nítorí ìyìn ni ó yẹ kí n gbà lọ́dọ̀ yín. Nítorí bí n kò tilẹ̀ jẹ́ nǹkankan, n kò rẹ̀yìn ninu ohunkohun sí àwọn aposteli yín tí ẹ kà kún pataki.


bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a wà ní ipò láti gba ìyìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Kristi. Ṣugbọn à ń ṣe jẹ́jẹ́ láàrin yín, àní gẹ́gẹ́ bí obinrin alágbàtọ́ tíí ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ tí ó ń tọ́jú.


Ẹnikẹ́ni wà láàrin yín tí ó gbọ́n, tí ó tún mòye? Kí ó fihàn nípa ìgbé-ayé rere ati ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí ó fi ọgbọ́n hàn.


Ṣugbọn kí ẹwà yín jẹ́ ti ọkàn tí kò hàn sóde, ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Èyí ni ẹwà tí kò lè ṣá, èyí tí ó ṣe iyebíye lójú Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan