Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 12:2 - Yoruba Bible

2 Wọn ń wí pé, “Ṣé Mose nìkan ni OLUWA ti lò láti bá eniyan sọ̀rọ̀ ni? Ṣé kò ti lo àwa náà rí?” OLUWA sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọn ń sọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Nwọn si wipe, Nipa Mose nikan ni OLUWA ha sọ̀rọ bi? kò ha ti ipa wa sọ̀rọ pẹlu? OLUWA si gbọ́ ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Wọ́n sì wí pé, “Nípa Mose nìkan ni Olúwa ti sọ̀rọ̀ bí, kò ha ti ipa wa sọ̀rọ̀ bí?” Olúwa sì gbọ́ èyí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 12:2
22 Iomraidhean Croise  

Ó tún lóyún, ó tún bí ọkunrin, ó ní, “Nítorí pé OLUWA ti gbọ́ pé wọ́n kórìíra mi ni ó ṣe fún mi ní ọmọ yìí pẹlu.” Ó bá sọ ọ́ ní Simeoni.


Nígbà tí àkókò ọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, Dafidi ní kí wọ́n mú un wá sí ààfin, Batiṣeba sì di aya rẹ̀. Ó bí ọmọkunrin kan fún un, ṣugbọn inú OLUWA kò dùn sí ohun tí Dafidi ṣe.


Ọba Asiria ti rán Rabuṣake, olórí ogun rẹ̀ kan, láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí Ọlọrun alààyè. Kí OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn yìí, kí ó sì jẹ àwọn tí wọ́n sọ ọ́ níyà. Nítorí náà, gbadura fún àwọn eniyan wa tí wọ́n kù.”


Inú bí OLUWA sí Mose, ó ní, “Ṣebí Aaroni, ọmọ Lefi, arakunrin rẹ wà níbẹ̀? Mo mọ̀ pé òun lè sọ̀rọ̀ dáradára; ó ń bọ̀ wá pàdé rẹ, nígbà tí ó bá rí ọ, inú rẹ̀ yóo dùn gidigidi.


Aaroni sọ gbogbo ohun tí OLUWA sọ fún Mose fún wọn, ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu náà lójú gbogbo àwọn àgbààgbà náà.


Lẹ́yìn náà, Mose ati Aaroni lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sọ fún un pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ pé, ‘Jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, kí wọ́n lè lọ ṣe àjọ̀dún kan fún mi ninu aṣálẹ̀.’ ”


Mose ati Aaroni bá lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn. Aaroni ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Farao ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ọ̀pá náà di ejò.


Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà, ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n.


Ó ṣeéṣe kí OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbọ́ iṣẹ́ tí ọba Asiria rán Rabuṣake, iranṣẹ rẹ̀, pé kí ó wá fi Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà, kí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ lórí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀! Nítorí náà gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè kí o gbadura fún àwọn eniyan tí ó kù.’ ”


Èmi ni mo sá mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí mo rà yín pada kúrò lóko ẹrú; tí mo rán Mose, Aaroni ati Miriamu láti ṣáájú yín.


Nígbà tí ó yá àwọn eniyan náà bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí OLUWA nípa ìṣòro wọn. Nígbà tí OLUWA gbọ́ kíkùn wọn, inú bí i, ó sì fi iná jó wọn; iná náà run gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní òpin ibùdó náà.


Mose dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń jowú nítorí mi? Inú mi ìbá dùn bí OLUWA bá lè fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ní ẹ̀mí rẹ̀ kí wọ́n sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.”


Mose ni ó jẹ́ oníwà ìrẹ̀lẹ̀ jù ninu gbogbo ẹni tí ó wà láyé.


Wọ́n dojú kọ Mose ati Aaroni, wọ́n ní, “Ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí kọjá ààyè yín, nítorí pé olukuluku àwọn ọmọ Israẹli ni ó jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, OLUWA sì ń bẹ láàrin wọn. Kí ló dé tí ẹ̀yin gbé ara yín ga ju gbogbo àwọn eniyan OLUWA lọ?”


Ẹ ní ìfẹ́ láàrin ara yín bíi mọ̀lẹ́bí. Ní ti bíbu ọlá fún ara yín, ẹ máa fi ti ẹnìkejì yín ṣiwaju.


Nítorí nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fún mi, mò ń sọ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan láàrin yín pé kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ jù bí ó ti yẹ lọ. Ṣugbọn kí olukuluku ronú níwọ̀n, kí ó máa ṣe jẹ́jẹ́, níwọ̀nba bí Ọlọrun ti pín ẹ̀bùn igbagbọ fún un.


Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú tabi iyàn jíjà,


Ẹ má ṣe ohunkohun pẹlu ẹ̀mí àṣehàn tabi láti gba ìyìn eniyan, ṣugbọn pẹlu ọkàn ìrẹ̀lẹ̀, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣiwaju ara yín.


Bákan náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ máa tẹríba fún àwọn àgbà. Gbogbo yín, ẹ gbé ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀, bí ẹ ti ń bá ara yín lò, nítorí, “Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga, ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan