Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 12:13 - Yoruba Bible

13 Mose ké pe Ọlọrun kí ó wò ó sàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 Mose si kigbe pè OLUWA, wipe, Ọlọrun, emi bẹ̀ ọ, mu u lara dá nisisiyi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Torí èyí Mose sì kígbe sí Olúwa, “Ọlọ́run, jọ̀wọ́, mú un láradá!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 12:13
23 Iomraidhean Croise  

Adura pẹlu igbagbọ yóo mú kí ara aláìsàn náà yá. Oluwa yóo gbé e dìde, a óo sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá jì í.


Má jẹ́ kí nǹkan burúkú borí rẹ, ṣugbọn fi ohun rere ṣẹgun nǹkan burúkú.


Ẹ máa súre fún àwọn tí ó ń gbe yín ṣépè. Ẹ máa gbadura fún àwọn tí wọn ń ṣe àìdára si yín.


Jesu ní, “Baba, dáríjì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọn ń ṣe.” Wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn.


Wò mí sàn, OLUWA, ara mi yóo sì dá, gbà mí, n óo sì bọ́ ninu ewu. Nítorí pé ìwọ ni mò ń yìn.


Òṣùpá yóo mọ́lẹ̀ bí oòrùn; oòrùn yóo mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po meje, ní ọjọ́ tí OLUWA yóo bá di ọgbẹ́ àwọn eniyan rẹ̀, tí yóo sì wo ọgbẹ́ tí ó dá sí wọn lára sàn.


“Ó dùn mí pé mo fi Saulu jọba. Ó ti yipada kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa òfin mi mọ́.” Inú bí Samuẹli, ó sì gbadura sí OLUWA ní gbogbo òru ọjọ́ náà.


Ní tèmi, n kò ní ṣẹ̀, nípa aigbadura sí OLUWA fun yín. N óo sì máa kọ yín ní ohun tí ó dára láti máa ṣe ati ọ̀nà tí ó tọ́ fun yín láti máa rìn.


Ní ọjọ́ keji gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose ati Aaroni pé, “Ẹ pa àwọn eniyan OLUWA.”


Gbogbo wọn ń kùn sí Mose ati Aaroni pé, “Ó sàn fún wa kí á kúkú kú sí Ijipti tabi ní aṣálẹ̀ yìí.


Ni ó bá kúnlẹ̀, ó kígbe, ó ní, “Oluwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.” Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó kú.


Abrahamu bá gbadura sí Ọlọrun, Ọlọrun sì wo Abimeleki sàn ati aya rẹ̀ ati àwọn ẹrubinrin rẹ̀, tí wọ́n fi lè bímọ,


Ọlọrun tún ní, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abíyá pada.” Mose sì ti ọwọ́ bọ abíyá rẹ̀ pada; nígbà tí ó yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ pada sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.


Àwọn eniyan náà sì ké tọ Mose wá fún ìrànlọ́wọ́. Mose gbadura fún wọn, iná náà sì kú.


Má jẹ́ kí ó dàbí ọmọ tí ó ti kú kí á tó bí i, tí apákan ara rẹ̀ sì ti jẹrà.”


OLUWA, Ọlọrun mi, mo ké pè ọ́, o sì wò mí sàn.


Mo ní, “OLUWA, ṣàánú mi kí o sì wò mí sàn; mo ti ṣẹ̀ ọ́.”


ó ní, “Bí ẹ bá farabalẹ̀ gbọ́ ohùn èmi OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, tí ẹ pa gbogbo òfin mi mọ́, tí ẹ sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà mi, èmi OLUWA kò ní fi èyíkéyìí ninu àwọn àrùn tí mo fi ṣe àwọn ará Ijipti ṣe yín, nítorí pé, èmi ni OLUWA, olùwòsàn yín.”


Jeroboamu ọba bẹ wolii náà pé, “Jọ̀wọ́, bẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì gbadura sí i pé kí ó wo apá mi sàn.” Wolii náà bá gbadura sí OLUWA, apá Jeroboamu ọba sì sàn, ó pada sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan