Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 12:1 - Yoruba Bible

1 Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ̀ òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ ọmọbinrin ará Kuṣi ní iyawo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 A TI Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ òdi si Mose nitori obinrin ara Etiopia ti o gbé ni iyawo: nitoripe o gbé obinrin ara Etiopia kan ni iyawo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Miriamu àti Aaroni sọ̀rọ̀-òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiopia.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 12:1
19 Iomraidhean Croise  

n óo sì mú kí o búra ní orúkọ OLUWA Ọlọrun ọ̀run ati ayé, pé o kò ní fẹ́ aya fún ọmọ mi lára àwọn ọmọbinrin ará Kenaani tí mò ń gbé,


Oluwa mi mú mi búra pé n kò gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ òun láàrin àwọn ará ilẹ̀ Kenaani tí òun ń gbé.


Rebeka sọ fún Isaaki, ó ní, “Ọ̀rọ̀ àwọn obinrin Hiti wọnyi mú kí ayé sú mi. Bí Jakọbu bá lọ fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn obinrin ará Hiti, irú àwọn obinrin ilẹ̀ yìí, irú ire wo ni ó tún kù fún mi láyé mọ́?”


Lẹ́yìn náà ó sọ Josẹfu ní orúkọ Ijipti kan, orúkọ náà ni Safenati Panea, ó sì fi Asenati, ọmọ Pọtifera, fún un láti fi ṣe aya. Pọtifera yìí jẹ́ babalóòṣà oriṣa Oni, ní ìlú Heliopolisi. Josẹfu sì lọ káàkiri ilẹ̀ Ijipti.


Àwọn ọmọbinrin meje kan wá pọn omi, wọ́n jẹ́ ọmọ Jẹtiro, alufaa ìlú Midiani. Wọ́n pọn omi kún ọpọ́n ìmumi àwọn ẹran, láti fún àwọn agbo ẹran baba wọn ní omi mu.


Mose gbà láti máa gbé ọ̀dọ̀ ọkunrin náà, ó bá fún un ní Sipora, ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin rẹ̀ láti fi ṣe aya.


Kó má baà wá di pé ẹ̀ ń fẹ́mọ lọ́wọ́ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín, kí àwọn ọmọbinrin yín má baà máa ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa, kí wọ́n sì mú kí àwọn ọmọkunrin yín náà máa ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn.


Kò gbọdọ̀ fi opó ṣe aya tabi obinrin tí ó kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, tabi obinrin tí ó ti mọ ọkunrin, tabi aṣẹ́wó; kò gbọdọ̀ fẹ́ èyíkéyìí ninu wọn. Obinrin tí kò tíì mọ ọkunrin rí ni kí ó fẹ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀.


àwọn eniyan wọnyi, tí wọ́n ti rí ògo mi ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe ní Ijipti ati ninu aṣálẹ̀, ṣugbọn tí wọ́n ti dán mi wò nígbà mẹ́wàá, tí wọ́n sì ṣàìgbọràn sí mi,


wọ́n kó aadọtaleerugba (250) ọkunrin tí wọ́n jọ jẹ́ olórí ati olókìkí ninu àwọn ọmọ Israẹli sòdí láti dìtẹ̀ mọ́ Mose.


Orúkọ aya Amramu ni Jokebedi, ọmọbinrin Lefi tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ijipti. Ó bí Aaroni ati Mose ati Miriamu, arabinrin wọn fún Amramu.


Ará ilé ẹni ni ọ̀tá ẹni.


Jesu dá a lóhùn pé, “Ta ni ìyá mi? Àwọn ta sì ni arakunrin mi?”


Ẹ ranti ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín, pé, ‘Ọmọ-ọ̀dọ̀ kò ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ṣe inúnibíni mi, wọn yóo ṣe inúnibíni yín. Bí wọ́n bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọn yóo pa ti ẹ̀yin náà mọ́.


(Àwọn arakunrin rẹ̀ kò gbà á gbọ́ ni wọ́n ṣe sọ bẹ́ẹ̀.)


Mo wá ti di ọ̀tá yín nítorí mo sọ òtítọ́ fun yín!


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan