Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 11:12 - Yoruba Bible

12 Ṣé èmi ni mo lóyún wọn ni, àbí èmi ni mo bí wọn, tí o fi sọ fún mi pé kí n gbé wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Iṣe emi li o lóyun gbogbo enia yi? iṣe emi li o bi wọn, ti iwọ fi wi fun mi pe, Ma gbé wọn lọ li õkanaiya rẹ, bi baba iti igbé ọmọ ọmú, si ilẹ ti iwọ ti bura fun awọn baba wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Èmi ni mo ha lóyún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí bí? Àbí èmi ló bí wọn? Tí ìwọ fi sọ fún mi pé, máa gbé wọn sí oókan àyà rẹ, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ ti máa ń gbe ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti búra láti fún àwọn baba ńlá wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 11:12
20 Iomraidhean Croise  

Gbogbo ilẹ̀ tí ò ń wò yìí, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún títí lae.


OLUWA Ọlọrun ọ̀run, tí ó mú mi jáde láti ilé baba mi, ati ilẹ̀ tí wọ́n bí mi sí, tí ó bá mi sọ̀rọ̀, tí ó sì búra fún mi pé, àwọn ọmọ mi ni òun yóo fi ilẹ̀ yìí fún, yóo rán angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ, o óo sì fẹ́ aya wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀.


Ọlọrun ní, “Máa gbé ilẹ̀ yìí, n óo wà pẹlu rẹ, n óo sì bukun ọ, nítorí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún ní ilẹ̀ wọnyi, n óo sì mú ìlérí mi fún Abrahamu, baba rẹ ṣẹ.


Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé, “Àtikú mi kù sí dẹ̀dẹ̀, ṣugbọn Ọlọrun yóo máa tọ́jú yín, yóo sì mu yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí, lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu.”


Ahabu ní aadọrin ọmọkunrin tí wọn ń gbé Samaria. Jehu kọ ìwé ranṣẹ sí àwọn olórí ìlú ati àwọn àgbààgbà ati àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu, ó ní:


Nítorí náà, ẹni tí ó ń ṣe ìtọ́jú ààfin ati olórí ìlú pẹlu àwọn àgbààgbà ati àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu ranṣẹ sí Jehu, wọ́n ní: “Iranṣẹ rẹ ni wá, a sì ti ṣetán láti ṣe ohunkohun tí o bá pa láṣẹ. A kò ní fi ẹnikẹ́ni sórí oyè, ṣe ohunkohun tí o bá rò pé ó dára.”


“Nígbà tí OLUWA bá mu yín dé ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ẹ̀yin ati àwọn baba yín, tí ó bá sì fún yín ní ilẹ̀ náà,


Nígbà tí Ọlọrun bá mu yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí ó ti búra fún àwọn baba yín pé òun yóo fi fún yín, tí ó kún fún wàrà ati oyin, ẹ óo máa ṣe ìsìn yìí ninu oṣù yìí lọdọọdun.


OLUWA tún pe Mose, ó ní, “Dìde kúrò níhìn-ín, ìwọ ati àwọn eniyan tí o kó wá láti ilẹ̀ Ijipti, ẹ lọ sí ilẹ̀ tí mo ti búra fún Abrahamu, ati fún Isaaki, ati fún Jakọbu pé n óo fún arọmọdọmọ wọn.


N óo sì ko yín wá sí ilẹ̀ tí mo búra láti fún Abrahamu, ati Isaaki ati Jakọbu; n óo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní, Èmi ni OLUWA.’ ”


Yóo bọ́ agbo ẹran bí olùṣọ́-aguntan. Yóo kó àwọn ọ̀dọ́ aguntan jọ sí apá rẹ̀, yóo gbé wọn mọ́ àyà rẹ̀. Yóo sì máa fi sùúrù da àwọn tí wọn lọ́mọ lẹ́yìn láàrin wọn.


OLUWA dáhùn pé, “Ǹjẹ́ abiyamọ le gbàgbé ọmọ tí ń fún lọ́mú? Ṣé ó le má ṣàánú ọmọ bíbí inú rẹ̀? Bí àwọn wọnyi tilẹ̀ gbàgbé. Èmi kò ní gbàgbé rẹ.


Àwọn ọba ni yóo máa tọ́jú rẹ bíi baba, àwọn ayaba yóo sì máa tọ́jú rẹ bí ìyá, ní ìdojúbolẹ̀ ni wọn óo máa tẹríba fún ọ, wọn óo sì máa pọ́n eruku ẹsẹ̀ rẹ lá. O óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA, ojú kò ní ti àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé mi.”


Olùṣọ́ kanṣoṣo ni n óo yàn fún wọn, òun náà sì ni Dafidi, iranṣẹ mi. Yóo máa bọ́ wọn, yóo sì máa ṣe olùṣọ́ wọn.


“Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-aguntan rere, mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan.


Nítorí pé, ẹ̀ báà ní ẹgbẹrun àwọn olùtọ́ ninu Kristi, ẹ kò ní ju ẹyọ baba kan lọ. Nítorí ninu Kristi Jesu, èmi ni mo bi yín nípa ọ̀rọ̀ ìyìn rere.


Ẹ̀yin ọmọ mi, ara ń ni mí nítorí yín, bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́, títí ẹ óo fi di àwòrán Kristi.


Ninu aṣálẹ̀ ńkọ́? Ṣebí ẹ rí i bí OLUWA Ọlọrun yín ti gbé yín, bí baba tíí gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ tọ̀ títí tí ẹ fi dé ibi tí ẹ wà yìí.


bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a wà ní ipò láti gba ìyìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Kristi. Ṣugbọn à ń ṣe jẹ́jẹ́ láàrin yín, àní gẹ́gẹ́ bí obinrin alágbàtọ́ tíí ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ tí ó ń tọ́jú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan