Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 11:10 - Yoruba Bible

10 Mose gbọ́ bí àwọn eniyan náà ti ń sọkún lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ wọn, olukuluku pẹlu àwọn ará ilé rẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà dun Mose, ibinu OLUWA sì ru sí àwọn eniyan náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Nigbana ni Mose gbọ́, awọn enia nsọkun ni idile wọn, olukuluku li ẹnu-ọ̀na agọ́ tirẹ̀: ibinu OLUWA si rú si wọn gidigidi; o si buru loju Mose.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Mose sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọkún ní gbogbo ìdílé wọn, oníkálùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tirẹ̀. Olúwa sì bínú gidigidi. Inú Mose sì bàjẹ́ pẹ̀lú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 11:10
19 Iomraidhean Croise  

Wọ́n ń kùn ninu àgọ́ wọn, wọn kò sì fetí sí ohùn OLUWA.


OLUWA, mo kórìíra àwọn tí ó kórìíra rẹ; mo sì kẹ́gàn àwọn tí ń dìtẹ̀ sí ọ?


Nítorí náà nígbà tí OLUWA gbọ́, inú bí i; iná mọ́ ìdílé Jakọbu, inú OLUWA sì ru sí àwọn ọmọ Israẹli;


Nígbà tí Ọlọrun gbọ́, inú bí i gidigidi; ó sì kọ Israẹli sílẹ̀ patapata.


Nítorí náà ni inú ṣe bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀, ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì pa wọ́n, àwọn òkè sì mì tìtì. Òkú wọn dàbí pàǹtí láàrin ìgboro, sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì dá ọwọ́ ìjà dúró.


Ìwà yín yóo mú kí ilẹ̀ tí mo fun yín bọ́ lọ́wọ́ yín; n óo sí sọ yín di ẹrú àwọn ọ̀tá yín ní ilẹ̀ tí ẹ kò mọ̀rí. Ẹ ti mú kí ibinu mi máa jó bí iná, kò sì ní kú títí lae.”


Nígbà tí ó yá àwọn eniyan náà bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí OLUWA nípa ìṣòro wọn. Nígbà tí OLUWA gbọ́ kíkùn wọn, inú bí i, ó sì fi iná jó wọn; iná náà run gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní òpin ibùdó náà.


Mose bá wí fún OLUWA pé, “Kí ló dé tí o ṣe mí báyìí? Kí ló dé tí n kò rí ojurere rẹ, tí o sì di ẹrù gbogbo àwọn eniyan wọnyi rù mí?


Òròòru ni mana náà máa ń bọ́ nígbà tí ìrì bá ń sẹ̀ ní ibùdó.


Mose ni ó jẹ́ oníwà ìrẹ̀lẹ̀ jù ninu gbogbo ẹni tí ó wà láyé.


Inú sì bí OLUWA sí àwọn mejeeji, ó sì kúrò lọ́dọ̀ wọn.


Àwọn eniyan náà bá kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn Kora ati Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu pẹlu aya ati àwọn ọmọ wọn jáde wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn.


wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun ati Mose, wọ́n ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó wa wá láti Ijipti, pé kí á wá kú ninu aṣálẹ̀ yìí? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi, burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí ti sú wa.”


Nígbà tí Jesu rí i inú bí i: ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí ti irú wọn ni ìjọba Ọlọrun.


Jesu wò yíká pẹlu ibinu, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí pé ọkàn wọn le. Ó wá wí fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ sì bọ́ sípò.


Nítorí iná ibinu mi ń jó, yóo sì jó títí dé isà òkú. Yóo jó ayé ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu rẹ̀ ní àjórun, tó fi mọ́ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan