Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 10:9 - Yoruba Bible

9 Nígbà tí ẹ bá ń lọ bá àwọn ọ̀tá yín jà lójú ogun láti gba ara yín lọ́wọ́ àwọn tí ń ni yín lára, ẹ óo fọn fèrè ìdágìrì. OLUWA Ọlọrun yín yóo sì ranti yín, yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Bi ẹnyin ba si lọ si ogun ni ilẹ nyin lọ ipade awọn ọtá ti nni nyin lara, nigbana ni ki ẹnyin ki o fi ipè fun idagiri; a o si ranti nyin niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, a o si gbà nyin lọwọ awọn ọtá nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Nígbà tí ẹ bá lọ jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀tá tó ń ni yín lára ní ilẹ̀ yín, ẹ fun ìpè ìdágìrì pẹ̀lú fèrè. A ó sì rántí yín níwájú Olúwa, Ọlọ́run yín yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 10:9
34 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn Ọlọrun ranti Noa, ati gbogbo ẹranko, ati ẹran ọ̀sìn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀. Nítorí náà, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fà.


Ọlọrun wà pẹlu wa, òun fúnrarẹ̀ ni aṣaaju wa. Àwọn alufaa rẹ̀ wà níhìn-ín láti fun fèrè láti pè wá kí á gbógun tì yín. Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ má ṣe bá OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín jà, nítorí ẹ kò ní borí.”


Nígbà tí Juda rí i pé ogun wà níwájú ati lẹ́yìn wọn, wọ́n ké pe OLUWA, àwọn alufaa sì fọn fèrè ogun.


Ranti mi, OLUWA, nígbà tí o bá ń ṣí ojurere wo àwọn eniyan rẹ. Ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń gbà wọ́n là.


Àwọn ọ̀tá wọn ni wọ́n lára, wọ́n sì fi agbára mú wọn sìn.


Òun ni ó ranti wa ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ wa, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;


Gbogbo aráyé, ẹ̀yin tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, nígbà tí a bá gbé àsíá sókè lórí àwọn òkè, ẹ wò ó, nígbà tí a bá fun fèrè ogun, ẹ gbọ́.


“Kígbe sókè, má dákẹ́, ké sókè bíi fèrè ogun, sọ ìrékọjá àwọn eniyan mi fún wọn ní àsọyé, sọ ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jakọbu fún wọn.


Oró ò! Oró ò! Mò ń jẹ̀rora! Àyà mi ò! Àyà mi ń lù kìkìkì, n kò sì lè dákẹ́; nítorí mo gbọ́ ìró fèrè ogun, ati ariwo ogun.


Yóo ti pẹ́ tó tí n óo máa wo àsíá ogun, tí n óo sì máa gbọ́ fèrè ogun?


Ẹ sọ ọ́ ní Juda, ẹ sì kéde rẹ̀ láàrin Jerusalẹmu pé, “Ẹ fọn fèrè káàkiri ilẹ̀ náà, kí ẹ sì kígbe sókè pé, ‘Ẹ kó ara yín jọ kí á lọ sí àwọn ìlú olódi.’


Nítorí náà, wò ó, àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ kí ariwo ogun sọ, ní Raba ìlú àwọn ọmọ Amoni; Raba yóo di òkítì àlàpà, a óo sì dáná sun àwọn ìgbèríko rẹ̀; Israẹli yóo wá pada fi ogun kó àwọn tí wọ́n kó o lẹ́rú.


Ẹ̀yin ọmọ Bẹnjamini, ẹ sá àsálà! Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu. Ẹ fọn fèrè ogun ní Tekoa, kí ẹ ṣe ìkìlọ̀ fún wọn ní Beti Hakikeremu, nítorí pé nǹkan burúkú ati ìparun ńlá ń bọ̀ láti ìhà àríwá.


Mo fi àwọn aṣọ́nà ṣọ́nà nítorí yín. Mo wí fún wọn pé, “Ẹ máa dẹtí sílẹ̀ sí fèrè ogun!” Ṣugbọn wọ́n ní, “A kò ní dẹtí sílẹ̀.”


Wọn óo fọn fèrè ogun, wọn óo múra ogun, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò ní jáde lọ sójú ogun nítorí ibinu mi ti dé sórí gbogbo wọn.


Ẹ fọn fèrè ní Gibea, ẹ fọn fèrè ogun ní Rama, ẹ pariwo ogun ní Betafeni, ogun dé o, ẹ̀yin ará Bẹnjamini!


pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ ya ọjọ́ kinni oṣù keje sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀. Yóo jẹ́ ọjọ́ ìrántí, ẹ óo kéde rẹ̀ pẹlu ìró fèrè, ẹ óo sì ní àpèjọ mímọ́.


“Ṣé eniyan lè fọn fèrè ogun láàrin ìlú kí àyà ará ìlú má já? “Àbí nǹkan ibi lè ṣẹlẹ̀ ní ìlú láìṣe pé OLUWA ni ó ṣe é?


Ọjọ́ ipè ogun ati ariwo ogun sí àwọn ìlú olódi ati àwọn ilé-ìṣọ́ gíga.


Mose sì rán wọn lọ sójú ogun lábẹ́ àṣẹ Finehasi ọmọ Eleasari alufaa, pẹlu àwọn ohun èlò mímọ́ ati fèrè fún ìdágìrì lọ́wọ́ rẹ̀.


Bí ohun tí fèrè ogun bá ń wí kò bá yé eniyan, ta ni yóo palẹ̀ mọ́ fún ogun?


“Nígbà tí ẹ bá jáde lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, tí ẹ bá rí ọpọlọpọ ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn, nítorí OLUWA Ọlọrun yín, tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wà pẹlu yín.


Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè ogun náà gidigidi, tí ẹ sì gbọ́ ìró rẹ̀, kí gbogbo àwọn eniyan hó yèè! Ògiri ìlú náà yóo sì wó. Kí olukuluku àwọn ọmọ ogun wọ inú ìlú náà lọ tààrà.”


Nígbà tí àwọn ará Sidoni, àwọn ará Amaleki, ati àwọn ará Maoni ń pọn yín lójú; ẹ kígbe pè mí, mo sì gbà yín lọ́wọ́ wọn.


Odidi ọdún mejidinlogun ni wọ́n fi ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní òdìkejì odò Jọdani, ní Gileadi lára. Gileadi yìí wà ní ilẹ̀ àwọn ará Amoni.


Nígbàkúùgbà tí OLUWA bá gbé aṣiwaju kan dìde fún wọn, OLUWA a máa wà pẹlu aṣiwaju náà, a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn, ní àkókò aṣiwaju náà. Ìkérora àwọn ọmọ Israẹli a máa mú kí àánú wọn ṣe OLUWA, nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá ń fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n sì ń ni wọ́n lára.


Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọn fèrè ní agbègbè olókè Efuraimu. Àwọn ọmọ Israẹli bá tẹ̀lé e lẹ́yìn láti agbègbè olókè, ó sì ṣiwaju wọn.


Ṣugbọn Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Gideoni, Gideoni bá fọn fèrè ogun, àwọn ọmọ Abieseri bá pe ara wọn jáde wọ́n bá tẹ̀lé e.


Mo gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati gbogbo àwọn tí wọn ń ni yín lára. Mo lé wọn jáde fún yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fun yín.


Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Mo kó yín jáde wá láti Ijipti, mo gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati gbogbo àwọn eniyan yòókù tí wọn ń ni yín lára.’


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan