Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 10:4 - Yoruba Bible

4 Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé fèrè kan ni wọ́n fọn, àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli nìkan ni yóo wá sọ́dọ̀ rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Bi o ba ṣepe ipè kan ni nwọn fun, nigbana ni ki awọn ijoye, olori ẹgbẹgbẹrun enia Israeli, ki o pejọ sọdọ rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan ni o fọn, nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli yóò péjọ síwájú rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 10:4
4 Iomraidhean Croise  

Ohun tí ó yẹ kí o ṣe nìyí, yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jẹ́ alákòóso, àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun, tí wọ́n ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, tí wọ́n sì kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀; fi wọ́n ṣe alákòóso àwọn eniyan wọnyi, fi àwọn kan ṣe alákòóso lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn kan lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn kan lórí araadọta, ati àwọn mìíràn lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá.


àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli, tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé wọn, tí wọ́n sì wà pẹlu Mose nígbà tí ó ka àwọn eniyan Israẹli,


Mo bá fi mú àwọn olórí olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, àwọn tí wọ́n gbọ́n tí wọ́n sì ní ìrírí, mo yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí fun yín. Mo fi àwọn kan jẹ balogun lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn lórí araadọta eniyan; bẹ́ẹ̀ ni mo fi àwọn ẹlòmíràn jẹ balogun lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá, mo sì fi àwọn kan ṣe olórí ninu gbogbo ẹ̀yà yín.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan