Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 10:25 - Yoruba Bible

25 Ní ìparí, àwọn ẹ̀yà tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun Dani ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Ahieseri ọmọ Amiṣadai ni olórí wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

25 Ọpágun ibudó awọn ọmọ Dani, ti o kẹhin gbogbo ibudó, si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: olori ogun rẹ̀ si ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 Lákòótan, àwọn ọmọ-ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dani lábẹ́ ọ̀págun wọn. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai ni ọ̀gágun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 10:25
12 Iomraidhean Croise  

Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun ṣáájú àwọn alufaa tí wọn ń fọn fèrè ogun, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu. Àwọn tí wọn ń fọn fèrè ogun sì ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́.


Ahieseri ọmọ Amiṣadai ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Dani.


“Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn bí ìgbà tí ilẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ara yín yóo sì tètè yá. Òdodo yín yóo máa tàn níwájú yín. Ògo mi yóo ṣe ààbò lẹ́yìn yín.


Nítorí pé ẹ kò ní fi ìkánjú jáde, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní sáré jáde. Nítorí OLUWA yóo máa lọ níwájú yín, Ọlọrun Israẹli yóo sì wà lẹ́yìn yín.


Ní ọjọ́ kẹwaa ni Ahieseri ọmọ Amiṣadai, olórí àwọn ẹ̀yà Dani mú ọrẹ tirẹ̀ wá.


Olórí ẹ̀yà Bẹnjamini sì ni Abidani ọmọ Gideoni.


Pagieli ọmọ Okirani ni olórí ẹ̀yà Aṣeri.


Àwọn alufaa meje tí wọ́n mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA kọjá siwaju, wọ́n sì ń fọn fèrè ogun wọn lemọ́lemọ́. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun wà níwájú wọn, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu OLUWA. Àwọn tí ń fọn fèrè ogun ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan