Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 10:2 - Yoruba Bible

2 “Fi fadaka tí wọ́n fi òòlù lù ṣe fèrè meji fún pípe àwọn ọmọ Israẹli jọ ati títú ibùdó palẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Iwọ ṣe ipè fadakà meji; iṣẹ́-ọnà lilù ni ki o ṣe wọn: iwọ o si ma fi wọn pè ajọ, iwọ o si ma fi wọn ṣí ibudó.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ṣe fèrè fàdákà méjì pẹ̀lú fàdákà lílù, kí o máa lò ó láti máa fi pe ìjọ ènìyàn àti láti máa fi darí ìrìnàjò lọ sí ibùdó yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 10:2
14 Iomraidhean Croise  

Wọn kò lò lára owó náà láti fi ra agbada fadaka, abọ́, fèrè, tabi àwọn ohun èlò wúrà tabi ti fadaka sí ilé OLUWA,


Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni, àwọn ọmọkunrin wọn ati àwọn ìbátan wọn dúró ní apá ìhà ìlà oòrùn pẹpẹ. Wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, wọ́n ń fi ìlù, hapu ati dùùrù kọrin; pẹlu ọgọfa alufaa tí wọ́n ń fi fèrè kọrin,


Ẹ fọn fèrè ní ọjọ́ oṣù titun, ati ní ọjọ́ oṣù tí a yà sọ́tọ̀, ati ní ọjọ́ àsè.


Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó mọ ìhó ayọ̀ nnì, àwọn tí ń rìn ninu ìmọ́lẹ̀ ojurere rẹ, OLUWA,


Fi wúrà tí wọ́n fi ọmọ owú lù ṣe Kerubu meji, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìtẹ́ àánú náà.


“Fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà kan. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ ati ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe é ní àṣepọ̀ mọ́ òkè ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà bí òdòdó tí wọn yóo fi dárà sí ìdí fìtílà kọ̀ọ̀kan.


Ẹ má mú ẹbọ asán wá fún mi mọ́; ohun ìríra ni turari jẹ́ fún mi. Àjọ̀dún ìbẹ̀rẹ̀ oṣù titun, ọjọ́ ìsinmi, ati pípe àpéjọ. Ara mi kò gba ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dàpọ̀ mọ́ ẹ̀sìn mọ́.


Ẹ sọ ọ́ ní Juda, ẹ sì kéde rẹ̀ láàrin Jerusalẹmu pé, “Ẹ fọn fèrè káàkiri ilẹ̀ náà, kí ẹ sì kígbe sókè pé, ‘Ẹ kó ara yín jọ kí á lọ sí àwọn ìlú olódi.’


OLUWA ní: “Ẹ ti fèrè bọnu, nítorí ẹyẹ igún wà lórí ilé mi, nítorí pé wọ́n ti yẹ àdéhùn tí mo bá wọn ṣe, wọ́n sì ti rú òfin mi.


Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì pe àpèjọ. Ẹ pe àwọn àgbààgbà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà jọ sí ilé OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì kígbe pe OLUWA.


Ẹ fun fèrè ní Sioni, ẹ kéde ìdágìrì lórí òkè mímọ́ mi. Kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà wárìrì, nítorí ọjọ́ OLUWA ń bọ̀, ó sì ti dé tán.


OLUWA sọ fún Mose pé,


Nígbà tí ẹ bá fẹ́ pe àwọn ọmọ Israẹli jọ ẹ óo máa fọn fèrè, ṣugbọn kò ní jẹ́ ti ìdágìrì.


Oluwa kan ṣoṣo ni ó wà, ati igbagbọ kan, ati ìrìbọmi kan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan