Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 10:12 - Yoruba Bible

12 Àwọn ọmọ Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn láti aṣálẹ̀ Sinai, wọ́n tò lẹ́sẹẹsẹ. Ìkùukùu náà bá dúró ní aṣálẹ̀ Parani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati ijù Sinai; awọsanma na si duro ni ijù Parani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Àwọn ọmọ Israẹli sì gbéra kúrò ní aginjù Sinai wọ́n sì rin ìrìnàjò wọn káàkiri títí tí ìkùùkuu fi dúró sí aginjù Parani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 10:12
22 Iomraidhean Croise  

ati àwọn ará Hori ní orí Òkè Seiri, títí dé Eliparani, lẹ́bàá aṣálẹ̀.


Ó ń gbé inú aginjù Parani, ìyá rẹ̀ sì fẹ́ aya fún un ní ilẹ̀ Ijipti.


Adadi ati àwọn iranṣẹ baba rẹ̀ wọnyi kúrò ní Midiani, wọ́n sì lọ sí Parani. Ní Parani yìí ni àwọn ọkunrin mìíràn ti para pọ̀ mọ́ wọn, tí gbogbo wọ́n sì jọ lọ sí Ijipti. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Farao, ọba Ijipti, ó fún Adadi ní ilé ati ilẹ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún un déédé.


Wọ́n gbéra láti Sukotu, wọ́n pàgọ́ sí Etamu létí aṣálẹ̀.


OLUWA wá láti Temani, Ẹni Mímọ́ sì wá láti òkè Parani. Ògo rẹ̀ bo ojú ọ̀run, gbogbo ayé sì kún fún ìyìn rẹ̀.


Ní ọjọ́ kinni oṣù keji, ní ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu Àgọ́ Àjọ, tí ó wà ninu aṣálẹ̀ Sinai, pé,


Wọ́n bá gbéra kúrò ní Sinai, òkè OLUWA, wọ́n rìn fún ọjọ́ mẹta. Àpótí Majẹmu OLUWA sì wà níwájú wọn láti bá wọn wá ibi ìsinmi tí wọn yóo pàgọ́ sí.


Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ni Haserotu, wọ́n sì pa àgọ́ wọn sí aṣálẹ̀ Parani.


Wọn tọ Mose, Aaroni, ati àwọn ọmọ Israẹli lọ ní Kadeṣi ní aṣálẹ̀ Parani. Wọ́n sọ gbogbo ohun tí ojú wọn rí, wọ́n sì fi èso tí wọ́n mú wá hàn wọ́n.


Mose bá rán àwọn ọkunrin tí wọ́n jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà wọn lọ, láti aṣálẹ̀ Parani.


Àwọn ọmọ Israẹli ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, wọ́n pàgọ́ ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe tẹ̀síwájú, olukuluku wà ninu ìdílé tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.


Ní oṣù kinni, ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu aṣálẹ̀ Sinai pé,


Nígbà tí ìkùukùu yìí bá kúrò ní orí Àgọ́ Àjọ àwọn ọmọ Israẹli yóo tú àgọ́ wọn palẹ̀, wọn yóo sì lọ tún un pa níbi tí ìkùukùu náà bá ti dúró.


Wọn sì ṣe é ní àṣáálẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ní aṣálẹ̀ Sinai. Àwọn eniyan náà ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fun wọn.


Ọ̀rọ̀ tí Mose bá àwọn eniyan Israẹli sọ ninu aṣálẹ̀ nìyí, ní òdìkejì odò Jọdani, ní Araba tí ó kọjú sí Sufu, láàrin Parani, Tofeli, Labani, Haserotu ati Disahabu.


“Gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wa ti pàṣẹ fún wa nígbà náà, a gbéra ní Horebu, a sì la àwọn aṣálẹ̀ ńláńlá tí wọ́n bani lẹ́rù kọjá, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe rí i ní ojú ọ̀nà àwọn agbègbè olókè àwọn ará Amori; a sì dé Kadeṣi Banea.


Ó ní kí á dìde, kí á bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí agbègbè olókè ti àwọn ará Amori, ati gbogbo agbègbè tí ó yí wọn ká ní Araba, ní àwọn agbègbè olókè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, ati èyí tí ó wà létí òkun tí wọn ń pè ní Mẹditarenia, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Lẹbanoni, títí dé odò ńlá nnì, àní odò Yufurate.


OLUWA wá láti orí òkè Sinai, ó yọ gẹ́gẹ́ bí oòrùn láti Edomu, ó ràn sórí àwọn eniyan rẹ̀ láti òkè Parani. Ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹgbaarun àwọn ẹni mímọ́, ó gbé iná tí ń jò lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.


Nígbà tí Samuẹli kú, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kó ara wọn jọ láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì sin òkú rẹ̀ sí ilé rẹ̀ ní Rama. Lẹ́yìn náà, Dafidi lọ sí aṣálẹ̀ Parani.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan