Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 10:10 - Yoruba Bible

10 Ẹ óo máa fọn àwọn fèrè náà ní ọjọ́ ayọ̀, ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún yín ati ní ọjọ́ kinni oṣù. Ẹ óo máa fọn wọ́n nígbà tí ẹ bá mú ọrẹ ẹbọ sísun ati ọrẹ ẹbọ alaafia yín wá fún Ọlọrun. Yóo jẹ́ àmì ìrántí fun yín níwájú Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Li ọjọ̀ ayọ̀ nyin pẹlu, ati li ajọ nyin, ati ni ìbẹrẹ oṣù nyin, ni ki ẹnyin ki o fun ipè sori ẹbọ sisun nyin, ati sori ẹbọ ti ẹbọ alafia nyin; ki nwọn ki o le ma ṣe iranti fun nyin niwaju Ọlọrun nyin: Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Bẹ́ẹ̀ náà ni ní ọjọ́ ayọ̀ yín, ní gbogbo àjọ̀dún tí a yàn àti ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yín, ni kí ẹ máa fun fèrè lórí ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà yín, wọn yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 10:10
34 Iomraidhean Croise  

Ọkọ rẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi fẹ́ lọ rí i lónìí? Òní kì í ṣe ọjọ́ oṣù tuntun tabi ọjọ́ ìsinmi.” Ó sì dáhùn pé, “Kò séwu.”


Àwọn alufaa tí wọ́n yàn láti máa fọn fèrè níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun ni: Ṣebanaya, Joṣafati, Netaneli, Amasa, Sakaraya, Bẹnaya, ati Elieseri. Obedi Edomu ati Jehaya pẹlu ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ibi tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu sí.


Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli ṣe gbé Àpótí Majẹmu OLUWA pẹlu ìró orin ayọ̀, tí wọn ń fi oríṣìíríṣìí ohun èlò orin bíi ipè, fèrè, aro, hapu ati dùùrù kọ.


Hemani ati Jedutuni ní fèrè, aro, ati àwọn ohun èlò ìkọrin mìíràn tí wọ́n fi ń kọrin ìyìn. Àwọn ọmọ Jedutuni ni wọ́n yàn láti máa ṣọ́ àwọn ẹnu ọ̀nà.


Àwọn ọmọ Lefi dúró pẹlu ohun èlò orin Dafidi, àwọn alufaa sì dúró pẹlu fèrè.


Ọba ati ìjọ eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí sin OLUWA, àwọn akọrin ń kọrin, àwọn afunfèrè ń fun fèrè títí tí ẹbọ sísun náà fi parí.


Àwọn alufaa dúró ní ipò wọn, àwọn ọmọ Lefi náà dúró láti kọrin sí OLUWA pẹlu ohun èlò orin tí Dafidi ṣe ati ìlànà tí ó fi lélẹ̀ láti máa fi kọrin ọpẹ́ sí OLUWA pé, “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ wà títí lae;” ní gbogbo ìgbà tí Dafidi bá lò wọ́n láti kọrin ìyìn. Àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè gbogbo eniyan yóo sì dìde dúró.


Nígbà tí àwọn mọlémọlé bẹ̀rẹ̀ sí fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀, àwọn alufaa gbé ẹ̀wù wọn wọ̀, wọ́n dúró pẹlu fèrè lọ́wọ́ wọn. Ìdílé Asafu, ẹ̀yà Lefi, ń lu kimbali wọn, wọ́n fí ń yin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ètò tí Dafidi, ọba Israẹli, ti ṣe.


Àwọn kan ninu àwọn ọmọ alufaa tẹ̀lé wọn pẹlu fèrè. Àwọn nìwọ̀nyí: Sakaraya, ọmọ Jonatani, ọmọ Ṣemaaya, ọmọ Matanaya, ọmọ Mikaaya, ọmọ Sakuri, ọmọ Asafu,


Ẹ fi ariwo fèrè yìn ín; ẹ fi fèrè ati hapu yìn ín.


Ẹ fọn fèrè ní ọjọ́ oṣù titun, ati ní ọjọ́ oṣù tí a yà sọ́tọ̀, ati ní ọjọ́ àsè.


Nítorí pé àṣẹ ni, fún àwọn ọmọ Israẹli, ìlànà sì ni, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Jakọbu.


Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó mọ ìhó ayọ̀ nnì, àwọn tí ń rìn ninu ìmọ́lẹ̀ ojurere rẹ, OLUWA,


“Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli yóo máa wà lára Aaroni, lórí ìgbàyà ìdájọ́, ní oókan àyà rẹ̀, nígbà tí ó bá wọ ibi mímọ́ lọ, fún ìrántí nígbà gbogbo níwájú OLUWA.


Gba owó ètùtù lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli, kí o sì máa lò ó fún iṣẹ́ ilé ìsìn àgọ́ àjọ, kí ó lè máa mú àwọn ọmọ Israẹli wá sí ìrántí níwájú OLUWA, kí ó sì lè jẹ́ ètùtù fún yín.”


Ní ọjọ́ náà, a óo fun fèrè ogun ńlá, àwọn tí ó ti sọnù sí ilẹ̀ Asiria ati àwọn tí a lé lọ sí ilẹ̀ Ijipti yóo wá sin OLUWA lórí òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.


pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ ya ọjọ́ kinni oṣù keje sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀. Yóo jẹ́ ọjọ́ ìrántí, ẹ óo kéde rẹ̀ pẹlu ìró fèrè, ẹ óo sì ní àpèjọ mímọ́.


Nígbà tí ẹ bá ń lọ bá àwọn ọ̀tá yín jà lójú ogun láti gba ara yín lọ́wọ́ àwọn tí ń ni yín lára, ẹ óo fọn fèrè ìdágìrì. OLUWA Ọlọrun yín yóo sì ranti yín, yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.


“Ẹ óo máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù. Àwọn nǹkan tí ẹ óo máa fi rúbọ ni: ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n.


“Ní ọjọ́ kinni oṣù keje, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan. Ó jẹ́ ọjọ́ tí ẹ óo máa fun fèrè.


“Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí ẹrù ìpọ́njú ń wọ̀ lọ́rùn. Èmi yóo fun yín ní ìsinmi.


Kọniliu bá tẹjú mọ́ ọn. Ẹ̀rù bà á, ó ní, “Kí ló dé, alàgbà?” Angẹli yìí bá sọ fún un pé, “Adura rẹ ti gbà; iṣẹ́ àánú rẹ ti gòkè lọ siwaju Ọlọrun. Ọlọrun sì ti ranti rẹ.


Nítorí nígbà tí ohùn àṣẹ bá dún, Olórí àwọn angẹli yóo fọhùn, fèrè Ọlọrun yóo dún, Oluwa fúnrarẹ̀ yóo sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Àwọn òkú ninu Jesu ni yóo kọ́kọ́ jinde.


Ẹ máa fi ọ̀rọ̀ wọnyi tu ara yín ninu.


Nígbà náà, ẹ óo dá wọn lóhùn pé omi odò Jọdani pín sí meji níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA nígbà tí wọn gbé e kọjá odò náà. Nítorí náà, àwọn òkúta wọnyi yóo jẹ́ ohun ìrántí ayérayé fún àwọn ọmọ Israẹli.”


Kí àwọn alufaa meje mú fèrè ogun kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu. Ní ọjọ́ keje ẹ óo yípo ìlú náà nígbà meje, àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè ogun wọn.


Ẹ̀mí ati Iyawo ń wí pé, “Máa bọ̀!” Ẹni tí ó gbọ́ níláti sọ pé, “Máa bọ̀.” Ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ kí ó wá, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mu omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.


Dafidi sọ fún un pé, “Ọ̀la ni ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, n kò sì gbọdọ̀ má bá ọba jókòó jẹun. Ṣugbọn jẹ́ kí n lọ farapamọ́ sinu pápá títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹta.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan