Numeri 10:1 - Yoruba Bible1 OLUWA sọ fún Mose pé, Faic an caibideilBibeli Mimọ1 OLUWA si sọ fun Mose pe, Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní1 Olúwa sọ fún Mose pé: Faic an caibideil |
Nígbà tí ó wo ọ̀kánkán, ó wò, ó rí ọba náà tí ó dúró ní ẹ̀bá òpó, ní ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí àṣà, ó sì rí i tí àwọn olórí ogun ati àwọn afunfèrè yí i ká, tí àwọn eniyan sì ń fi ayọ̀ pariwo, tí wọ́n sì ń fọn fèrè. Atalaya fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó sì kígbe pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí! Ọ̀tẹ̀ nìyí!”
ó rí i tí ọba náà dúró lẹ́bàá òpó lẹ́nu ọ̀nà, àwọn ọ̀gágun ati àwọn tí wọn ń fọn fèrè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo eniyan ń hó ìhó ayọ̀, wọ́n ń fọn fèrè, àwọn tí ń lo ohun èlò orin ń fi wọ́n kọrin, àwọn eniyan sì ń gberin. Nígbà tí Atalaya rí nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ẹ̀rù bà á, ó sì kígbe lóhùn rara pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí! Ọ̀tẹ̀ nìyí!”
Àwọn alufaa dúró ní ipò wọn, àwọn ọmọ Lefi náà dúró láti kọrin sí OLUWA pẹlu ohun èlò orin tí Dafidi ṣe ati ìlànà tí ó fi lélẹ̀ láti máa fi kọrin ọpẹ́ sí OLUWA pé, “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ wà títí lae;” ní gbogbo ìgbà tí Dafidi bá lò wọ́n láti kọrin ìyìn. Àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè gbogbo eniyan yóo sì dìde dúró.