Numeri 1:4 - Yoruba Bible4 Kí ọkunrin kọ̀ọ̀kan, láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan wà pẹlu yín láti máa ràn yín lọ́wọ́. Àwọn ọkunrin tí yóo máa ràn yín lọ́wọ́ gbọdọ̀ jẹ́ baálẹ̀ ní àdúgbò wọn.” Faic an caibideilBibeli Mimọ4 Ki ọkunrin kọkan lati inu olukuluku ẹ̀ya ki o si wà pẹlu nyin; ki olukuluku jẹ́ olori ile awọn baba rẹ̀. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní4 Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan láti inú olúkúlùkù ẹ̀yà kí ó sì wá pẹ̀lú yín, kí olúkúlùkù jẹ́ olórí ilé àwọn baba rẹ̀. Faic an caibideil |
Ohun tí ó yẹ kí o ṣe nìyí, yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jẹ́ alákòóso, àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun, tí wọ́n ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, tí wọ́n sì kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀; fi wọ́n ṣe alákòóso àwọn eniyan wọnyi, fi àwọn kan ṣe alákòóso lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn kan lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn kan lórí araadọta, ati àwọn mìíràn lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá.
Mo bá fi mú àwọn olórí olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, àwọn tí wọ́n gbọ́n tí wọ́n sì ní ìrírí, mo yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí fun yín. Mo fi àwọn kan jẹ balogun lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn lórí araadọta eniyan; bẹ́ẹ̀ ni mo fi àwọn ẹlòmíràn jẹ balogun lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá, mo sì fi àwọn kan ṣe olórí ninu gbogbo ẹ̀yà yín.