Numeri 1:3 - Yoruba Bible3 Ìwọ ati Aaroni, ẹ ka gbogbo àwọn tí wọ́n lè jáde lọ sí ojú ogun, láti ẹni ogún ọdún lọ sókè. Ẹ kà wọ́n ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, ati ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Faic an caibideilBibeli Mimọ3 Lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli, iwọ ati Aaroni ni ki o kaye wọn gẹgẹ bi ogun wọn. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní3 Ìwọ àti Aaroni ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun. Faic an caibideil |
Amasaya pe àwọn eniyan Juda ati Bẹnjamini jọ, ó pín wọn sábẹ́ àwọn ọ̀gágun ní ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ ni gbogbo àwọn tí ó kó jọ. Gbogbo wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) akọni ọkunrin tí wọ́n tó lọ sójú ogun, tí wọ́n sì lè lo ọ̀kọ̀ ati apata.