Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 1:26 - Yoruba Bible

26 Ninu ẹ̀yà Juda, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

26 Ti awọn ọmọ Juda, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

26 Láti ìran Juda: Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 1:26
12 Iomraidhean Croise  

Ó tún lóyún ó sì tún bí ọkunrin, ó ní, “Wàyí o, n óo yin OLUWA,” ó bá sọ ọ́ ní Juda. Lẹ́yìn rẹ̀, kò bímọ mọ́.


Àwọn ọmọ ti Juda ni: Eri, Onani, Ṣela, Peresi, ati Sera, (ṣugbọn, Eri ati Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani) àwọn ọmọ ti Peresi ni Hesironi ati Hamuli.


Joabu sọ iye àwọn eniyan tí ó kà fún ọba: Ogoji ọ̀kẹ́ (800,000) ni àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun jà ní ilẹ̀ Israẹli, àwọn ti ilẹ̀ Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdọgbọn (500,000).


Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà Juda di ẹ̀yà tí ó lágbára ju gbogbo ẹ̀yà yòókù lọ, tí wọ́n sì ń jọba lórí wọn, sibẹsibẹ ipò àkọ́bí jẹ́ ti àwọn ọmọ Josẹfu).


ṣugbọn ó yan ẹ̀yà Juda, ó sì yan òkè Sioni tí ó fẹ́ràn.


jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé aadọta lé ní ẹgbẹjọ (45,650).


jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogoji ó lé ẹgbẹta (74,600).


Abrahamu bí Isaaki, Isaaki bí Jakọbu, Jakọbu bí Juda ati àwọn arakunrin rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan