Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 1:2 - Yoruba Bible

2 “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Israẹli, ní agbo-ilé agbo-ilé, ati ìdílé-ìdílé; kí ẹ sì kọ orúkọ gbogbo àwọn ọkunrin sílẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ẹ kaye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, olukuluku ọkunrin, nipa ori wọn;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Israẹli nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 1:2
16 Iomraidhean Croise  

Àwọn eniyan Israẹli gbéra, wọ́n rìn láti Ramesesi lọ sí Sukotu. Iye àwọn eniyan náà tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ọkunrin, láìka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde.


“Nígbà tí o bá ka iye àwọn eniyan Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ mú ohun ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ wá fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn, nígbà tí o bá kà wọ́n.


Fadaka tí àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn eniyan náà dájọ jẹ́ ọgọrun-un ìwọ̀n talẹnti, ati ẹẹdẹgbẹsan ìwọ̀n ṣekeli ó lé marundinlọgọrin (1,775), ìwọ̀n tí wọ́n máa ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n dá wúrà ati fadaka ati idẹ yìí jọ.


Olukuluku àwọn tí wọ́n tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n kà dá ìdajì ìwọ̀n ṣekeli kọ̀ọ̀kan tí òfin wí, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ilé OLUWA ni wọ́n sì fi wọ̀n ọ́n, iye àwọn eniyan tí wọ́n kà jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́, ati ẹgbẹtadinlogun ó lé aadọjọ (603,550).


pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn ọkunrin mejila náà, wọ́n kọ orúkọ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀, láti ẹni ogún ọdún sókè, ní agbo-ilé agbo-ilé, ati ní ìdílé-ìdílé.


Mose kà wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu aṣálẹ̀ Sinai gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.


Ninu ẹ̀yà Simeoni, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan