Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 1:16 - Yoruba Bible

16 Àwọn ni olórí tí a yàn ninu àwọn ọmọ Israẹli, olukuluku wọn jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà wọn, ati ní ìdílé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Wọnyi li awọn ti a yàn ninu ijọ, olori ẹ̀ya awọn baba wọn, awọn olori ẹgbẹgbẹrun ni Israeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Israẹli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 1:16
20 Iomraidhean Croise  

Ohun tí ó yẹ kí o ṣe nìyí, yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jẹ́ alákòóso, àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun, tí wọ́n ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, tí wọ́n sì kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀; fi wọ́n ṣe alákòóso àwọn eniyan wọnyi, fi àwọn kan ṣe alákòóso lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn kan lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn kan lórí araadọta, ati àwọn mìíràn lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá.


Mose yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè ṣe alákòóso ninu àwọn eniyan Israẹli, ó fi wọ́n ṣe olórí àwọn eniyan náà, àwọn kan jẹ́ alákòóso fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn, fún ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn, fún araadọta, àwọn mìíràn fún eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá.


OLUWA ní, “Ṣugbọn, ìwọ Bẹtilẹhẹmu ní Efurata, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kéré láàrin gbogbo ẹ̀yà Juda, sibẹ láti inú rẹ ni ẹni tí yóo jẹ́ aláṣẹ Israẹli yóo ti jáde wá fún mi, ẹni tí ìran tí ó ti ṣẹ̀ jẹ́ ti ayérayé, tí ó ti wà láti ìgbà laelae.”


Ahira ọmọ Enani ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Nafutali.


Mose ati Aaroni pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ ní ọjọ́ kinni oṣù keji,


Kí ọkunrin kọ̀ọ̀kan, láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan wà pẹlu yín láti máa ràn yín lọ́wọ́. Àwọn ọkunrin tí yóo máa ràn yín lọ́wọ́ gbọdọ̀ jẹ́ baálẹ̀ ní àdúgbò wọn.”


Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé fèrè kan ni wọ́n fọn, àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli nìkan ni yóo wá sọ́dọ̀ rẹ.


N óo wá bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀. N óo mú lára ẹ̀mí tí ó wà lára rẹ, n óo fi sí wọn lára; kí wọn lè máa ràn ọ́ lọ́wọ́, láti gbé ẹrù àwọn eniyan náà, kí ìwọ nìkan má baà máa ṣe iṣẹ́ náà.


wọ́n kó aadọtaleerugba (250) ọkunrin tí wọ́n jọ jẹ́ olórí ati olókìkí ninu àwọn ọmọ Israẹli sòdí láti dìtẹ̀ mọ́ Mose.


Eliabu bí Nemueli, Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu yìí ni wọ́n jẹ́ olókìkí eniyan láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ni wọ́n bá Mose ati Aaroni ṣe gbolohun asọ̀ nígbà tí Kora dìtẹ̀, tí wọ́n tako OLUWA.


Mose sọ fún àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli àwọn ohun tí OLUWA pa láṣẹ:


àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli, tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé wọn, tí wọ́n sì wà pẹlu Mose nígbà tí ó ka àwọn eniyan Israẹli,


Mo bá fi mú àwọn olórí olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, àwọn tí wọ́n gbọ́n tí wọ́n sì ní ìrírí, mo yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí fun yín. Mo fi àwọn kan jẹ balogun lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn lórí araadọta eniyan; bẹ́ẹ̀ ni mo fi àwọn ẹlòmíràn jẹ balogun lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá, mo sì fi àwọn kan ṣe olórí ninu gbogbo ẹ̀yà yín.


Gideoni dáhùn, ó ní, “Sọ fún mi OLUWA, báwo ni mo ṣe lè gba Israẹli sílẹ̀? Ìran mi ni ó rẹ̀yìn jùlọ ninu ẹ̀yà Manase, èmi ni mo sì kéré jù ní ìdílé wa.”


Ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀; ó ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ará Bẹnjamini, ṣé ọmọ Jese yìí yóo fún olukuluku yín ní oko ati ọgbà àjàrà? Ṣé yóo sì fi olukuluku yín ṣe olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀?


Ẹ mọ gbogbo ibi tíí máa ń sá pamọ́ sí dájúdájú, kí ẹ sì wá ròyìn fún mi. N óo ba yín lọ; bí ó bá wà níbẹ̀, n óo wá a kàn, bí ó bá tilẹ̀ wà láàrin ẹgbẹẹgbẹrun eniyan ilẹ̀ Juda.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan