Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 1:1 - Yoruba Bible

1 Ní ọjọ́ kinni oṣù keji, ní ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu Àgọ́ Àjọ, tí ó wà ninu aṣálẹ̀ Sinai, pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, ninu agọ́ ajọ, li ọjọ́ kini oṣù keji, li ọdún keji, ti nwọn jade lati ilẹ Egipti wá, wipe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní aginjù Sinai nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ó wí pé:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 1:1
15 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí ó di ọrinlenirinwo (480) ọdún tí àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ní ọdún kẹrin tí Solomoni gun orí oyè ní Israẹli, ní oṣù Sifi, tíí ṣe oṣù keji ọdún náà, ni ó bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé OLUWA.


Ní oṣù kẹta tí àwọn eniyan Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n dé aṣálẹ̀ Sinai.


Refidimu ni wọ́n ti gbéra wá sí aṣálẹ̀ Sinai. Nígbà tí wọ́n dé aṣálẹ̀ yìí, wọ́n pàgọ́ wọn siwaju òkè Sinai.


Níbẹ̀ ni n óo ti máa pàdé rẹ; láti òkè ìtẹ́ àánú, ní ààrin àwọn Kerubu mejeeji tí wọ́n wà lórí àpótí ẹ̀rí ni n óo ti máa bá ọ sọ nípa gbogbo òfin tí mo bá fẹ́ fún àwọn eniyan Israẹli.


Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni ọdún keji ni wọ́n pa àgọ́ náà.


“Kọ́ àgọ́ ìpàdé ní ọjọ́ kinni oṣù kinni.


OLUWA pe Mose, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú Àgọ́ Àjọ ó ní,


Àwọn òfin tí a ti kà sílẹ̀ wọnyi ni OLUWA fún Mose lórí Òkè Sinai fún àwọn ọmọ Israẹli.


pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn ọkunrin mejila náà, wọ́n kọ orúkọ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀, láti ẹni ogún ọdún sókè, ní agbo-ilé agbo-ilé, ati ní ìdílé-ìdílé.


Lójijì, OLUWA sọ fún Mose, Aaroni, ati Miriamu pé, “Ẹ wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.”


Ní oṣù kinni, ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu aṣálẹ̀ Sinai pé,


Ní ọjọ́ kinni oṣù kọkanla, ní ogoji ọdún tí wọ́n ti kúrò ní Ijipti, ni Mose bá àwọn eniyan Israẹli sọ ohun tí OLUWA pàṣẹ fún un láti sọ fún wọn;


Lẹ́yìn ọdún mejidinlogoji gbáko tí a ti kúrò ní Kadeṣi Banea, ni a tó kọjá odò Seredi, títí tí gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun ún jà ninu ìran náà fi run tán patapata, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti búra pé yóo rí.


“Ẹ ranti bí OLUWA Ọlọrun yín ti bukun yín ninu gbogbo ohun tí ẹ dáwọ́lé, ó sì ti tọ́jú yín ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀ ń rìn kiri ninu aṣálẹ̀ ńláńlá yìí. Ó ti wà pẹlu yín láti ogoji ọdún sẹ́yìn wá, ohunkohun kò sì jẹ yín níyà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan