Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 9:2 - Yoruba Bible

2 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹfa, Jesu mú Peteru ati Jakọbu ati Johanu lọ sí orí òkè gíga kan, àwọn mẹta yìí nìkan ni ó mú lọ. Ìrísí rẹ̀ bá yipada lójú wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Lẹhin ijọ mẹfa Jesu si mu Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, o si mu wọn lọ sori òke giga li apakan awọn nikan: ara rẹ̀ si yipada niwaju wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu lọ sí orí òkè gíga ní apá kan. Kò sí ẹlòmíràn pẹ̀lú wọn, ara rẹ̀ sì yípadà níwájú wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 9:2
23 Iomraidhean Croise  

Ojú yín yóo rí ọba ninu ọlá ńlá rẹ̀; ẹ óo fojú yín rí ilẹ̀ tí ó lọ salalu.


Kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun àfi Peteru ati Jakọbu ati Johanu àbúrò Jakọbu.


Ó wá mú Peteru, Jakọbu ati Johanu pẹlu rẹ̀. Àyà bẹ̀rẹ̀ sí pá a, ó bẹ̀rẹ̀ sí dààmú.


Mose bá gbéra, òun ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀, ó gun orí òkè Ọlọrun lọ.


Ẹẹkẹta nìyí tí n óo wá sọ́dọ̀ yín. Lẹ́nu ẹlẹ́rìí meji tabi mẹta ni a óo sì ti mọ òtítọ́ gbogbo ọ̀rọ̀.


Ó dàgbà níwájú rẹ̀ bí nǹkan ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rúwé ati bíi gbòǹgbò láti inú ilẹ̀ gbígbẹ. Ìrísí rẹ̀ kò dára, ojú rẹ̀ kò fanimọ́ra, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ẹwà tí ìbá fi wu eniyan.


Nígbà tí Ahabu lọ jẹun, Elija gun orí òkè Kamẹli lọ, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì ki orí bọ ààrin orúnkún rẹ̀ mejeeji.


Mo wá rí ìtẹ́ funfun ńlá kan ati ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀. Ayé ati ọ̀run sálọ fún un, a kò rí ààyè fún wọn mọ́.


Lẹ́yìn náà, ó fara han àwọn meji kan ninu wọn ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn lọ sí ìgbèríko kan.


ẹni tí yóo tún ara ìrẹ̀lẹ̀ wa ṣe kí ó lè dàbí ara tirẹ̀ tí ó lógo, gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tí ó fi lè fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ ara rẹ̀.


Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí ẹ para dà, kí ọkàn yín di titun, kí ẹ lè mòye ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun, tí ó dára, tí ó yẹ, tí ó sì pé.


Ọ̀rọ̀ náà wá di eniyan, ó ń gbé ààrin wa, a rí ògo rẹ̀, ògo bíi ti Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́.


Ní ọjọ́ kan, Jesu lọ sí orí òkè, ó lọ gbadura. Gbogbo òru ni ó fi gbadura sí Ọlọrun.


Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkan tí eniyan kò sí, kí ó lè dá wà. Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, wọ́n gba ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ láti ìlú wọn, wọ́n tẹ̀lé e.


Lẹ́yìn náà, ó to igi sórí pẹpẹ, ó gé akọ mààlúù náà sí wẹ́wẹ́, ó sì tò wọ́n sórí igi. Ó ní kí wọ́n pọn ẹ̀kún ìkòkò omi ńlá mẹrin, kí wọ́n dà á sórí ẹbọ ati igi náà, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan