Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 8:2 - Yoruba Bible

2 “Àánú àwọn eniyan wọnyi ń ṣe mí, nítorí ó di ọjọ́ mẹta tí wọ́n ti wà pẹlu mi, wọn kò ní ohun tí wọn yóo jẹ mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ãnu ijọ enia nṣe mi, nitoriti o di ijọ mẹta nisisiyi ti nwọn ti wà lọdọ mi, nwọn kò si li ohun ti nwọn o jẹ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ó wí fún wọn pé, “Àánú ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí nítorí pé ó tó ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti wà níhìn-ín, kò sì sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún wọn láti jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 8:2
23 Iomraidhean Croise  

Ó wò yíká, ó sì rí ìṣù àkàrà kan, ati ìkòkò omi kan lẹ́bàá ìgbèrí rẹ̀. Ó jẹun, ó mu omi, ó sì tún dùbúlẹ̀.


Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀.


Ojú gbogbo eniyan ń wò ọ́, o sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àsìkò.


Aláàánú ni OLUWA, olóore sì ni; kì í yára bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀.


O óo tún ṣàánú wa, o óo sì fẹsẹ̀ tẹ ẹ̀ṣẹ̀ wa ní àtẹ̀parẹ́. O óo sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa sí ìsàlẹ̀ òkun.


Bí ó ti ń gúnlẹ̀, ó rí ọ̀pọ̀ eniyan. Àánú wọn ṣe é, ó bá wo àwọn tí wọ́n ṣàìsàn ninu wọn sàn.


Àánú wọn ṣe Jesu, ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n lójú. Wọ́n ríran lẹsẹkẹsẹ, wọ́n bá ń tẹ̀lé e.


Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ eniyan náà, àánú wọn ṣe é nítorí wọ́n dàbí aguntan tí kò ní olùṣọ́, tí ọkàn wọn dààmú, tí ó sì rẹ̀wẹ̀sì.


Àánú ṣe Jesu ó bá na ọwọ́ ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́. Di mímọ́.”


Ṣugbọn Jesu kọ̀ fún un, ó sọ fún un pé, “Lọ sí ilé rẹ, sọ́dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sọ ohun tí Oluwa ti ṣe fún ọ ati bí ó ti ṣàánú rẹ.”


Wọ́n bá bọ́ sinu ọkọ̀ ojú omi kan, wọ́n fẹ́ yọ́ lọ sí ibi tí kò sí eniyan.


Nígbà tí Jesu jáde ninu ọkọ̀ ó rí ọpọlọpọ eniyan, àánú ṣe é nítorí wọ́n dàbí aguntan tí kò ní olùṣọ́. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan.


Bí mo bá ní kí wọn túká lọ sí ilé wọn ní ebi, yóo rẹ̀ wọ́n lọ́nà, nítorí àwọn mìíràn ninu wọn ti ọ̀nà jíjìn wá.”


Ó ní, “Nígbà pupọ ẹ̀mí náà á gbé e sọ sinu iná tabi sinu omi, kí ó lè pa á. Ṣugbọn bí ìwọ bá lè ṣe ohunkohun, ṣàánú wa kí o ràn wá lọ́wọ́.”


Ó bá dìde, ó lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀. “Bí ó ti ń bọ̀ ní òkèèrè ni baba rẹ̀ ti rí i. Àánú ṣe é, ó yára, ó dì mọ́ ọn lọ́rùn, ó bá fẹnu kò ó ní ẹnu.


Nígbà tí Oluwa rí obinrin náà, àánú rẹ̀ ṣe é. Ó sọ fún un pé, “Má sunkún mọ́.”


Nítorí náà, dandan ni kí òun alára jọ àwọn arakunrin rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà, kí ó lè jẹ́ Olórí Alufaa tí ó láàánú, tí ó sì ṣe é gbójú lé nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ níwájú Ọlọrun fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan.


Nítorí Olórí Alufaa tí a ní kì í ṣe ẹni tí kò lè bá wa kẹ́dùn ninu àwọn àìlera wa. Ṣugbọn ó jẹ́ ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bíi wa, ṣugbọn òun kò dẹ́ṣẹ̀.


Ó lè fi sùúrù bá àwọn tí wọ́n ṣìnà nítorí wọn kò gbọ́ lò, nítorí pé eniyan aláìlera ni òun náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan