Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 7:9 - Yoruba Bible

9 Jesu tún wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni pé ẹ pa àṣẹ Ọlọrun tì, kí ẹ lè mú àṣẹ ìbílẹ̀ yín ṣẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin kọ̀ ofin Ọlọrun silẹ, ki ẹnyin ki o le pa ofin atọwọdọwọ ti nyin mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ó si wí fún wọn: “Ẹ̀yin sá à mọ̀ bí ẹ ti ń gbé òfin Ọlọ́run jù sẹ́yìn kí ẹ lè mú òfin tiyín ṣẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 7:9
16 Iomraidhean Croise  

OLUWA, ó tó àkókò fún ọ láti ṣe nǹkankan, nítorí àwọn eniyan ń rú òfin rẹ.


Àwọn tí ń gbé inú ayé ti ba ilé ayé jẹ́, nítorí pé wọ́n ti rú àwọn òfin wọ́n ti tàpá sí àwọn ìlànà wọ́n sì da majẹmu ayérayé.


OLUWA ní, “Nítorí pé ẹnu nìkan ni àwọn eniyan wọnyi fi ń súnmọ́ mi, ètè lásán ni wọ́n sì fi ń yìn mí; ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi. Òfin eniyan, tí wọn kọ́ sórí lásán, ni ìbẹ̀rù mi sì jẹ́ fún wọn.


“Ohun tí ó bá wu ọba náà ni yóo máa ṣe; yóo gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo oriṣa lọ, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo máa sọ̀rọ̀ tó lòdì sí Ọlọrun àwọn ọlọrun, yóo sì bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i títí ọjọ́ ibinu tí a dá fún un yóo fi pé; nítorí pé ohun tí Ọlọrun ti pinnu yóo ṣẹ.


Yóo sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹni Gíga Jùlọ, yóo sì dá àwọn eniyan mímọ́, ti Ẹni Gíga Jùlọ lágara. Yóo gbìyànjú láti yí àkókò ati òfin pada. A óo sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́ fún ọdún mẹta ati ààbọ̀.


Ẹ fi àṣà ìbílẹ̀ yín yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ọpọlọpọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ tún ń ṣe.”


(Nítorí pé àwọn Farisi ati gbogbo àwọn Juu yòókù kò jẹ́ jẹun láì wẹ ọwọ́ ní ọ̀nà tí òfin là sílẹ̀; wọ́n ń tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn.


Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò fi tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀, tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?”


Ṣé Òfin wá di òtúbáńtẹ́ nítorí igbagbọ ni? Rárá o! A túbọ̀ fi ìdí Òfin múlẹ̀ ni.


Nítorí ẹ̀ ń fi ààyè gba àwọn ẹlòmíràn tí wọn ń wá waasu Jesu yàtọ̀ sí bí a ti waasu rẹ̀, ẹ sì ń gba ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti kọ́ gbà.


Ninu ẹ̀sìn Juu, mo ta ọpọlọpọ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ninu orílẹ̀-èdè mi yọ. Mo ní ìtara rékọjá ààlà ninu àṣà ìbílẹ̀ àwọn baba-ńlá mi.


Kì í ṣe pé mo pa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tì. Nítorí bí eniyan bá lè di olódodo nípa ṣíṣe iṣẹ́ òfin, a jẹ́ pé Kristi kàn kú lásán ni.


Yóo lòdì sí ohun gbogbo tí ó jẹ́ ti Ọlọrun tabi tí ó jẹ mọ́ ti ẹ̀sìn. Yóo gbé ara rẹ̀ ga ju èyíkéyìí ninu àwọn oriṣa lọ; yóo tilẹ̀ lọ jókòó ninu Tẹmpili Ọlọrun, yóo sì fi ara hàn pé òun ni Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan