Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 7:6 - Yoruba Bible

6 Jesu wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni Aisaya sọ ní àtijọ́ nípa ẹ̀yin àgàbàgebè, tí ó sì kọ ọ́ báyìí pé, ‘Ọlọrun wí pé: Ẹnu ni àwọn eniyan wọnyi fi ń yẹ́ mi sí, ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 O dahùn o si wi fun wọn pe, Otitọ ni Isaiah sọtẹlẹ nipa ti ẹnyin agabagebe, bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia yi nfi ète wọn bọla fun mi, ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Jesu dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òtítọ́ ni wòlíì Isaiah ń sọtẹ́lẹ̀ nípa tí ẹ̀yin àgàbàgebè, bí a ti kọ ọ́ pé: “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún mi ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 7:6
14 Iomraidhean Croise  

OLUWA ní, “Nítorí pé ẹnu nìkan ni àwọn eniyan wọnyi fi ń súnmọ́ mi, ètè lásán ni wọ́n sì fi ń yìn mí; ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi. Òfin eniyan, tí wọn kọ́ sórí lásán, ni ìbẹ̀rù mi sì jẹ́ fún wọn.


Wọ́n ń fi ẹnu jẹ́wọ́ pé àwọn mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n ń sẹ́ ẹ ninu ìwà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹlẹ́gbin ati aláìgbọràn, wọn kò yẹ fún iṣẹ́ rere kan.


Wọ́n ń wá sọ́dọ̀ rẹ bí àwọn eniyan tií wá, wọ́n sì ń jókòó níwájú rẹ bí eniyan mi. Wọ́n ń gbọ́ ohun tí ò ń wí, ṣugbọn wọn kò ní ṣe é; nítorí pé ẹnu lásán ni wọ́n fi ń sọ pé wọ́n ní ìfẹ́ pupọ, ṣugbọn níbi èrè tí wọn ó jẹ ni ọkàn wọn wà.


Ní òde, ara wọn dàbí olùfọkànsìn, ṣugbọn wọn kò mọ agbára ẹ̀sìn tòótọ́. Ìwọ jìnnà sí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀.


Ṣugbọn mo mọ̀ yín, mo sì mọ̀ pé ẹ kò ní ìfẹ́ Ọlọrun ninu yín.


Bí n kò bá ṣe irú iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ mi, sibẹ wọ́n kórìíra èmi ati Baba mi.


Nígbà tí ohùn wọn kò dọ́gba láàrin ara wọn, wọ́n bá ń túká lọ. Paulu wá tún sọ gbolohun kan, ó ní, “Òtítọ́ ni Ẹ̀mí Mímọ́ sọ láti ẹnu wolii Aisaya sí àwọn baba-ńlá yín.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan