Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 7:5 - Yoruba Bible

5 Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò fi tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀, tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Nigbana li awọn Farisi ati awọn akọwe bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko rìn gẹgẹ bi ofin atọwọdọwọ awọn àgba, ṣugbọn nwọn nfi ọwọ aimọ́ jẹun?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Nítorí èyí àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò tẹ̀lé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà nítorí wọ́n fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 7:5
12 Iomraidhean Croise  

“Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò fi tẹ̀lé àṣà tí àwọn baba wa fi lé wa lọ́wọ́? Nítorí wọn kì í wẹ ọwọ́ wọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ jẹun.”


Ẹ fi àṣà ìbílẹ̀ yín yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ọpọlọpọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ tún ń ṣe.”


“Ẹ fi àṣẹ Ọlọrun sílẹ̀, ẹ wá dìmọ́ àṣà eniyan.”


Jesu tún wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni pé ẹ pa àṣẹ Ọlọrun tì, kí ẹ lè mú àṣẹ ìbílẹ̀ yín ṣẹ.


Wọ́n ń sọ nípa rẹ pé ò ń kọ́ gbogbo àwọn Juu tí ń gbé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pé kí wọ́n yapa kúrò ninu ìlànà Mose. Wọ́n ní o sọ pé kí wọn má kọ ọmọ wọn nílà; àtipé kí wọn má tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn mọ́.


Mú wọn, kí o lọ bá wọn wẹ ẹ̀jẹ́ náà kúrò. San gbogbo owó tí wọn óo bá ná ati tìrẹ náà. Kí wọn wá fá orí wọn. Èyí yóo jẹ́ kí gbogbo eniyan mọ̀ pé kò sí òótọ́ ninu gbogbo nǹkan tí wọn ń sọ nípa rẹ. Wọn yóo mọ̀ pé Juu hánún-hánún ni ọ́ àtipé ò ń pa Òfin Mose mọ́.


ó sì di baba fún àwọn tí ó kọlà ṣugbọn tí wọn kò gbẹ́kẹ̀lé ilà tí wọ́n kọ, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní irú ọ̀nà igbagbọ tí baba wa Abrahamu ní kí ó tó kọlà.


Ninu ẹ̀sìn Juu, mo ta ọpọlọpọ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ninu orílẹ̀-èdè mi yọ. Mo ní ìtara rékọjá ààlà ninu àṣà ìbílẹ̀ àwọn baba-ńlá mi.


Nítorí a gbọ́ pé àwọn kan ninu yín ń rìn ségesège, wọn kì í ṣiṣẹ́ rárá, ẹsẹ̀ ni wọ́n fi í máa wọ́lẹ̀ kiri.


Ẹ̀yin ará, à ń pàṣẹ fun yín ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi pé kí ẹ yẹra fún àwọn onigbagbọ tí wọn bá ń rìn ségesège, tí wọn kò tẹ̀lé ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan