Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 7:4 - Yoruba Bible

4 Bí wọn bá ti ọjà dé, wọ́n kò jẹ́ jẹun láìjẹ́ pé wọ́n kọ́kọ́ wẹ̀. Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni ó ti di àṣà wọn, gẹ́gẹ́ bíi fífọ àwo ìmumi, ìkòkò ìpọnmi ati àwọn àwo kòtò onídẹ.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Nigbati nwọn ba si ti ọjà bọ̀, bi nwọn ko ba wẹ̀, nwọn ki ijẹun, ọ̀pọlọpọ ohun miran li o si wà, ti nwọn ti gbà lati mã fiyesi, bi fifọ ago, ati ikòko, ati ohunèlo idẹ, ati akete.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Nígbà tí wọ́n bá sì ti ọjà dé sílé, wọn kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan oúnjẹ àfi tí wọ́n bá bu omi wẹ ara wọn. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ogunlọ́gọ̀ àpẹẹrẹ òfin àti ìlànà tí wọ́n ti dì mú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, bí i fífọ kọ́ọ̀bù, àwọn ìkòkò, àti kẹ́tù.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 7:4
15 Iomraidhean Croise  

Ọwọ́ mi mọ́, n kò ní ẹ̀bi, OLUWA, mo sì ń jọ́sìn yí pẹpẹ rẹ ká.


Ẹ wẹ̀, kí ara yín dá ṣáká. Ẹ má hùwà burúkú níwájú mi mọ́. Ẹ má ṣe iṣẹ́ ibi mọ́.


Mo gbé ìgò ọtí kalẹ̀ níwájú àwọn ọmọ Rekabu, mo kó ife tì í. Mo bá sọ fún wọn pé, “Ó yá, ẹ máa mu ọtí waini.”


Ìwọ Jerusalẹmu, fọ ibi dànù kúrò lọ́kàn rẹ, kí á lè gbà ọ́ là. Yóo ti pẹ́ tó tí èrò burúkú yóo fi máa wà lọ́kàn rẹ?


“Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn. Ẹ̀ ń fọ òde ife ati òde àwo oúnjẹ nígbà tí inú wọn kún fún àwọn ohun tí ẹ fi ìwà olè ati ìwà ìmọ-tara-ẹni-nìkan já gbà.


Ìwọ afọ́jú Farisi! Kọ́kọ́ fọ inú ife ná, òde rẹ̀ náà yóo sì mọ́.


Nígbà tí Pilatu rí i pé òun kò lè yí wọn lọ́kàn pada, ati pé rògbòdìyàn fẹ́ bẹ́ sílẹ̀, ó mú omi, ó fọ ọwọ́ rẹ̀ níwájú wọn. Ó ní, “N kò lọ́wọ́ ninu ikú ọkunrin yìí. Ẹ̀yin ni kí ẹ mójútó ọ̀ràn náà.”


“Ẹ fi àṣẹ Ọlọrun sílẹ̀, ẹ wá dìmọ́ àṣà eniyan.”


Ìkòkò òkúta mẹfa kan wà níbẹ̀, tí wọ́n ti tọ́jú fún omi ìwẹ-ọwọ́-wẹ-ẹsẹ̀ àwọn Juu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó bíi garawa omi marun-un tabi mẹfa.


Ọ̀rọ̀ nípa ìwẹ̀mọ́ di àríyànjiyàn láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati ọkunrin Juu kan.


Ohun tí a rí dì mú ninu wọn kò ju nípa jíjẹ ati mímu lọ, ati nípa oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìwẹ ọwọ́, wẹ ẹsẹ̀. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìlànà àwọn nǹkan tí a lè fojú rí, tí yóo sì máa wà títí di àkókò àtúnṣe.


Ẹ súnmọ́ Ọlọrun, òun óo sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín dá ṣáká, ẹ̀yin oníyèméjì.


Ṣugbọn bí a bá ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, bí òun náà ti wà ninu ìmọ́lẹ̀, a ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ̀ Jesu Ọmọ rẹ̀ sì ti wẹ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa nù kúrò lára wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan