Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 6:2 - Yoruba Bible

2 Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé. Ẹnu ya ọpọlọpọ àwọn tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Wọ́n ń wí pé, “Níbo ni eléyìí ti kọ́ ẹ̀kọ́? Irú ọgbọ́n wo ni ọgbọ́n tirẹ̀ yìí, tí iṣẹ́ ìyanu ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Nigbati o si di ọjọ isimi, o bẹ̀rẹ si ikọni ninu sinagogu; ẹnu si yà awọn enia pipọ ti o gbọ́, nwọn wipe, Nibo li ọkunrin yi gbé ti ri nkan wọnyi? irú ọgbọ́n kili eyi ti a fifun u, ti irú iṣẹ agbara bayi nti ọwọ́ rẹ̀ ṣe?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí Sinagọgu láti kọ́ àwọn ènìyàn: ẹnu sì ya àwọn ènìyàn púpọ̀ tí ó gbọ́. Wọ́n wí pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí gbé ti rí nǹkan wọ̀nyí? Irú ọgbọ́n kí ni èyí tí a fi fún un, tí irú iṣẹ́ ìyanu báyìí ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 6:2
11 Iomraidhean Croise  

Jesu wá ń kiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó tún ń wo oríṣìíríṣìí àrùn sàn lára àwọn eniyan.


Nígbà tí Jesu parí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi, ẹnu ya àwọn eniyan sí ẹ̀kọ́ rẹ̀;


Ó bá lọ, ó ń waasu ninu àwọn ilé ìpàdé wọn ní gbogbo ilẹ̀ Galili, ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.


Nígbà tí Jesu dìde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Judia, ó rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Ọpọlọpọ àwọn eniyan tún lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó tún ń kọ́ wọn.


Ẹnu ya gbogbo àwọn tí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí òye rẹ̀ ati nítorí bí ó ṣe ń dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọn ń bi í.


Ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu àwọn ilé ìpàdé wọn. Gbogbo eniyan sì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere.


Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Ṣebí Jesu ọmọ Josẹfu ni; ẹni tí a mọ baba ati ìyá rẹ̀? Ó ṣe wá sọ pé, láti ọ̀run ni òun ti sọ̀kalẹ̀ wá?”


Ẹnu ya àwọn Juu, wọ́n ń sọ pé, “Báwo ni eléyìí ti ṣe mọ ìwé tó báyìí nígbà tí kò lọ sí ilé-ìwé?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan