Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 4:5 - Yoruba Bible

5 Irúgbìn mìíràn bọ́ sí orí òkúta tí erùpẹ̀ díẹ̀ bò lórí. Láìpẹ́, wọ́n yọ sókè nítorí erùpẹ̀ ibẹ̀ kò jinlẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Diẹ si bọ́ sori ilẹ apata, nibiti kò li erupẹ̀ pipọ; lojukanna o si ti hù jade, nitoriti kò ni ijinlẹ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Láìpẹ́ ọjọ́, ó hu jáde.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 4:5
11 Iomraidhean Croise  

Ó ní, mo sọ pé, n óo fún wọn ní ọkàn kan, n óo fi ẹ̀mí titun sí wọn ninu. N óo yọ ọkàn òkúta kúrò láyà wọn, n óo sì fún wọn ní ọkàn ẹran;


N óo fun yín ní ọkàn titun, n óo sì fi ẹ̀mí titun si yín ninu. N óo yọ ọkàn tí ó le bí òkúta kúrò, n óo sì fun yín ní ọkàn tí ó rọ̀ bí ẹran ara.


Ẹ gbin òdodo fún ara yín, kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ tí kì í yẹ̀; ẹ lọ dá oko sí ilẹ̀ tí ẹ ti kọ̀ sílẹ̀, nítorí ó tó àkókò láti wá OLUWA, kí ó lè wá rọ ìgbàlà le yín lórí bí òjò.


Ṣé ẹṣin a máa sáré lórí àpáta? Àbí eniyan a máa fi àjàgà mààlúù pa ilẹ̀ lórí òkun? Ṣugbọn ẹ ti sọ ẹ̀tọ́ di májèlé, ẹ sì ti sọ èso òdodo di ohun kíkorò.


Irúgbìn ti orí ilẹ̀ olókùúta ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó fi tayọ̀tayọ̀ gbà á lẹsẹkẹsẹ.


Bí ó ti ń fúnrúgbìn lọ, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ bá wá, wọ́n ṣà á jẹ.


Nígbà tí oòrùn mú, ó jó wọn pa, nítorí wọn kò ní gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀; wọ́n bá kú.


Àwọn tí ó bọ́ sórí òkúta ni àwọn tí ó gbọ́, tí wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, ṣugbọn wọn kò ní gbòǹgbò. Wọ́n gbàgbọ́ fún àkókò díẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ìdánwò dé, wọ́n bọ́hùn.


Irúgbìn mìíràn bọ́ sórí àpáta. Nígbà tí ó hù, ó bá gbẹ nítorí kò sí omi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan